Monday, January 30, 2017

RA ‘DATA’ LÓWÓ PỌ́KÚ KÍ O JÈRÈ Ẹ̀RỌ-ÌBÁNISỌ̀RỌ̀.



Ilé-iṣẹ́ tó ń rí sí ìbára-enisọ̀rọ̀ lórí ẹ̀rọ, GLO tún ti fi hàn pé àwọn lọ̀gá nínú pípèsè ‘data’ olówó pọ́kú. Wọn ò fún wa ní ‘data’ lówó pọ́kú nìkan, wọń tún fi ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ si. Ètò náà lọ báyìí:

·   
     Ta bá san ẹ̀ẹ́dẹ́gbaajọ náírà (#15,000) , a ma rí 1.4GB lóṣùn tàbí 17GB lọ́dún kan.

·     
   Ta bá san ẹgbàasań náírà (#18,000), a ma rí 1.8GB lóṣùn tàbí 21GB lọ́dún kan.


Àwọn ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ tó tẹ̀lẹ ni:
 Innjoo Halo.
    Wiko sunset.

    Wiko Lenny.

    Alcatel pixi 3.


Ẹ̀rọ-ìbánisọ̀rọ̀ kan ló ma tọ́sí wa ta bá sanwo, kìí ṣe mẹ́rèẹ̀rin. A ó sì ní àǹfàní láti mú nínú oṣooṣù tàbí ọdún kan.


Wọ́n ti ṣe irú ètò yí rí ní ọdún tó kọjá, kò sì pẹ́ nílẹ̀. Èyí ni pé ìjáfara léwu.

Fún ìbéèrè, ẹ lè kàn sí:

WEBSITE

  FACEBOOK

TWITTER 

ÀWỌN OLÓGUN KAN NA ÒJÍṢẸ́ ỌLỌ́RUN DÁKÚ NÍTORÍ...




Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ti ìjọ Ìràpadà t’Ọlọ́run (RCCG), Alex Ochienu ló sọ bí ológun méjì ṣe na òun títí t’óùn fi dákú nítorí wọ́n ní kí òun fa etí, kí óun sì ma kúrú-ga. Éyí tí òun kọ láti ṣe.

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí òjíṣẹ́ Ọlọ́run náà sọ, Cpl. M. Dankwa ló kọ́kọ́ nàá kí ológun kejì tí kò mọ orúkọ ẹ̀ to fọwọ́ kun. Ó sọ síwájú si pé wọ́n na òun tí òun sì dákú. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn tó wà nítòsí ló gbé òun lọ sí ilé-ìwòsàn tìjọba tó wà ní Gwarimpa ni Abuja.

Sunday, January 29, 2017

BÀÁLÙ-ÒFURUFÚ TI TINÚBU NI WỌ́N FI KÓ ...




Bàálù òfurufú tí wọ́n fi gbé ọ̀gbẹ́ni Yahyah Jammeh lọ sí orílẹ́-èdè Guinea jẹ́ ti Bọ́lá Tinúbu. Ó gbe é lẹ̀ kí ọ̀gbẹ́ni Jammeh fi kúrò ní Gambia, kí wàhálà má bàá ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.

Fún ìgbà mélòó tó kù kí ọ̀gbẹ́ni Jammeh lọ fara sinko sí orílẹ̀-èdè Guinea ni ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe owó ìlú kúmọkùmọ, ó tún fi bàálù-òfurufú akẹ́rù kó ọkọ̀ bọ̀gìnì-bọ̀gìnì kúrò ní Gambia. Ìròyìn sọ pé owó tó kó ju mílíọ̀nù mẹ́wàá dọ́là lọ.

Ẹnìkan tó súnmọ́ Aṣìwájú sọ pé bàálù-òfurufú náà ti wà lọ́dọ̀ Aàrẹ tìlú Guinea tipẹ́ nítorí ọ̀rẹ́ ni Tinúbu àti Aàrẹ náà. Bàálú náà gbé ọ̀gbẹ́ni Yahyah Jammeh, ìyàwó ẹ̀, ọmọ ẹ̀ àti ọ̀gbẹ́ni Conde tíí ṣe Aàrẹ orílẹ̀-èdè Guinea kúrò ní Gambia ni ọjọ́ ajé.          #Post-Nigeria

BÓ ṢE Ń LỌ NÍNÚ BỌ́Ọ̀LÚ-AFASẸ̀GBÁ ti ife-ẹ̀yẹ orílẹ̀-èdè adúláwọ̀




Lọ́sẹ̀yí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè ló ti padà sí ibi tí wọ́n ti wá. Ìfagagbága náà ti wọ ìpele ‘gbuarter final’.


Àwọn orílẹ̀-èdè tó pegedé, tó ma kó pa níí ìpele yìí ni: BurkinaFaso, Cameroon, Tunisia, Senegal, D.R. Congo, Morocco, Egypt àti Ghana.


Tunisia ma kojú BurkinaFaso ni ago márùn-ún, ní ago mẹ́jọ alẹ́ ni Senegal àti Cameroon ma jọ wọ̀yáàjà. Ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ìfagagbága ma wáyé.


D.R. Congo ma gbéjà fún Ghana ni ago márùn-ún ìrọ̀lẹ́, Egypt àti Morocco ma f’àgbà han’ra wọn ní ago mẹ́jọ. ọjọ́ àìkú ni èyí ma wáyé.

Thursday, January 26, 2017

SULTAN TÌLÚ SOKOTO ÀTI ÀWỌN GÓMÍNÀ ÌHÀ ÀRÍWÁ ṢÉ’PÀDÉ.




Ní ọjọ́ ajé ni Sultan tìlú Sokoto pẹ̀lú gbogbo gómínà ìhà àríwá ṣe ìpàdé lórí wàhàlà tó ń ṣẹlẹ̀ ní apá gúsù ilẹ̀ Kaduna. Nínú ìpàdé yìí lati rí àwọn ìjòyè ìlú, wọ́n ṣe ìpàdé nàá ní ilé e Kashim Ibrahim.

Sultan tìlú Sokoto bu ẹnu àtẹ̀ lu àwọn tó ń wàásù jàgídíjàgan. Ó sọ pé ìyà tó ń jẹ ìhà náà ló ń fa wàhálà ní bẹ̀. Ó ní kí wọ́n fẹnu kò sí àláfíà.

Alága àjọ gómínà ìhà àríwá, gómínà Borno Kashim Shettima ọ pé gbogbo ìhà Nàíjíríà tókù ni ìlọsíwájú. Ó sọ síwájú pé ìṣẹ́ jẹ́ nǹkan àkọ́kọ́ tó ń fa ọwọ́ ago wọn sẹ́yìn ni ìhà àríwá. Ó ní ní oṣùn keje ọdún 2013, àwọn kan gba ẹgbẹ̀rún márùn-ún láti bá àwọn BH tọ́jú ìbọn, iye kan náà ni wọn ma ń fún àwọn ọmọdé tí wọ́n bá fẹ́ rán wọn níṣẹ́ burúkú.

Gómínà tìlú Kaduna, Nasir El-Rufai sọ pé àwọn ìjòyè ìlú ló lè parí wàhálà náà.