Láti bí ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn ni ìròyìn ti ń gbe pé ó ṣeéṣe
ki ìgbeyàwó Tonto Dikeh àti Ọlákúnlé dàrú nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń fì wọ́n.
Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ri kà ní entertainment.naij, ìkan lára ọmọ
ọ̀dọ̀ ẹ̀ ló sọ pé Tonto Dikeh ti padà sí ìgbé-ayé ẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ìgbé-ayée lílo
ògùn olóró, èyí tó ma ń jẹ́ kó ṣìwàwù. Ìwà tó ń wù yì ló mú ọkọ ẹ̀ Ọlákúlé Ọládùnní
rìnìn àjò lọ Ghana bóyá kí òun tó dé ó lè ti yípadà.
Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sọ pé nítorí ògùn olóró yìí, Tonto Dikeh ma
ń ba nǹkan jẹ́ nílé. Ó ní ó ti ti ìyá ọkọ ẹ̀ ṣubú rí nígbàtí ó wá fún ilé ṣíṣí.
Ṣe bí a mọ̀ pé ìròyìn òkèrè bí ò lékan, á díkan. Ẹ jẹ́ ka
ṣe sùúrù ka ma retí láti ẹnu Tonto fúnra ẹ̀ nítorí ẹnu oníkàn latí ń gbọ́ pọ̀un.
No comments:
Post a Comment