Ọ̀gbẹ́ni Yahyah Jammeh ti fàáké kọ́rí láti gbé ìjọba fún ọ̀gbẹ́ni
Adama Barrow tí borí nínú ìdìbò ọjọ́ kínní, oṣùn kéjìlá ọdún tó kọjá. Ọ̀gbẹ́ni
Yahyah Jammeh ti wà lórí àléfà fún ọdún méjìlélógún kó tó wá gbà láti ṣe ìdìbò
náà. Àìfé fi àléfà sílẹ̀, àwọn mínísítà kànkan ti kọ̀wé fiṣẹ́ sílẹ̀. Bóyá èyí
ló bí ọ̀gbẹ́ni jammeh nínú ló fi fún àwọn tókù níwèé tó sì ń dá ṣè’jọba.
Àjọ AU àti ECOWAS ti jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn kò faramọ àti pé
kìí ṣé aàrẹ Gambia. Láti fi èyí hàn, wọ́n ṣe ayẹyẹ ìbúra fún ọ̀gbẹ́ni Adama
Barrow ní orílè-èdè Senegal ní ọjọ́ kọnkọ̀ndínlógún oṣùn yí. Àjọ ECOWAS ti fi
àwọn ọmọ-ogun sí ojúbodè orílẹ̀-èdè Senegal tó wọ orílẹ̀-èdè Gambia. Wọ́n lérí
láti yọ ọ̀gbẹ́ni Jammeh ní tipátipá.
Orílẹ̀-èdè Senegal ti kọ̀wé sí àjọ àgbáyé UN, láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Wọ́n fi ìwé nà ránṣẹ́ sí orílẹ̀-èdè
márùndínlógún tó wà ní igbimọ́ àbò.
![]() |
| Ộgbẹ́ ni Yahyah Jammeh ń fi ìlú sílẹ̀. (àwòrán láti Aljazeera) |
Lọ́jọ́ ẹtì ọ̀sẹ̀ yí ni ynaija.com jẹ́ ka mọ̀ pé ilé-iṣẹ́
ìròyìn Faransé @FRANCE24 tẹ̀ẹ́ sórí
twitter pé ọ̀gbẹ́ni Jammeh ti gbà láti gbé ìjọba sílẹ̀.
SOURCES: REUTERS, SAHARAREPORTERS, YNAIJA, ALJAZEERA


No comments:
Post a Comment