Thursday, January 26, 2017

ÌJỌBA ÀPAPỌ̀ FẸ́ BẸ̀RẸ̀ ÈTÒ ÌLERA Ọ̀FẸ́ FÚN ÀWỌN NIGER DELTA.




Usani Usani tó jẹ́ Mínísítà fún iṣe Niger Delta sọ pé ìjọba àpapọ̀ ma bẹ̀rẹ̀ ètò ìlera ọ̀fẹ́ ní àwọn ìjọba ìpínlẹ̀ mẹ́sàn-án tó ń pèsè petrol ní oṣùn tó ń bọ̀.

Usani sọ èyí nínú ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nu-wò tí NAN ṣe ní ọjọ́ ajé. Ó sọ pé ètò yí ma wáyé pẹ̀lú àjọṣepọ̀ ajọ̀ Urology, NAU. Wọ́n gbé ètò yí kalẹ̀ nítorí àǹfàní tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ń rí ní agbègbè náà. Iṣẹ́ ìjọba ni láti ri pé ìlera tó péye wà ní àrọ́wọ́tó wọn. 



#YNAIJA

No comments:

Post a Comment