Àwọn mẹ́fà kan ni àjọ EFCC mú pé wípé wọ́n ta àpò ìrẹsì
èyí tó wà fún àwọn tí BH lé nílé ní ìlú Maiduguri. Umar Ibrahim tó jẹ́
alábojútó ẹ̀ka ohun-ọ̀gbìn ní ìjọba ìbílẹ̀ Mafa ni ó ta àpò ìrẹsì ọgọ́rùn-ún mẹ́ta
èyí tó wà fún àwọn tí Boko Haram sọ di aláìnílé ní ìjọba ìbílẹ̀ náà. Àwọn
‘Danish Refugee Councel’ (DRC) ló fi àwọn àpò ìrẹsì náà tawọ́n lọ́re.
Àwọn afunrasí tí wọ́n mú pẹ̀lú ọ̀gbẹ́ni Ibrahim ni;
Bulama Ali Ṣangebe àti Modu Bulma tí ó jẹ́wọ́ pé alága ìbílẹ̀ ni ó sọpé kí àwọ́n
ta àwọn àpò ìrẹsì náà. Wọ́n tàá fún ọ̀gbẹ́ni Umar Salisu, wọ́n ta àpò kànkan ni
8500*.

No comments:
Post a Comment