Ògbóntarìgì òṣèré obìnrin, Ìyábọ̀ Òjó ti gba àwọn obìrin
níyànjú irúfẹ́ ọkọ tó dáa ju láàárín èyí tó ń yan-àlè àti èyí tó ń lu ìyàwó ẹ̀.
Ìyábọ̀ Òjó ń fi irúfẹ́ àwọn ọkùnrin bàyìí wéra, ó jẹ́ ka mọ̀ pé ìkan san ju
ìkejì lọ.
Ó jẹ́ ka mọ̀ pé àwọn ọkùnrin tó ń yan-àlè sàn tí irúfẹ́ ọkùnrin
bẹ́ẹ̀ ò bá ṣe é délé. Ó ní ohun kan tí ọkùnrin tó ń lu ìyàwó fẹ́ ni kí inú
ìyàwó náà má dùn èyí tí kò dára fún obìnrin.
Ó ní tí ọkùnrin bá wà tó ń tọ́jú ẹbí ẹ̀ tó wá ń ṣe ṣìná
níta, irúfẹ́ ọkùnrin bẹ ṣì ṣeé bá gbélé. Ṣùgbọ́n tí ọkọ bà fi ojoójúmọ́ na
ìyàwó ẹ̀, tí ìyàwó náà sì ń paá mọ́ra àfàìmọ̀ kó má jẹ̀ẹ́ ikú ló ń bò mọ́ra.
Ìyábọ̀ Òjó ló ń dá tọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ méjì, Festus àti
Priscilla làti bí ọdún mẹ́wàá báyìí. Ó dáwa lójú pé ó mọ ohun tó ń sọ.
No comments:
Post a Comment