Thursday, January 19, 2017

ÈDÈ YORÙBÁ.





Èdè Yorùbá jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èdè tí wọ́n sọ ní orílẹ́-èdè Benin, Togo, Braṣil, USA àti pàápàá jùlọ orílẹ́-èdè Nigeria. Àwọn èèyàn tó ń sọ èdè náà tó ogbọ̀n mílíọ́nù. Èdè alohùn ni ó jẹ́, àmì ohùn ṣe pàtàkì ta bá ń kọ èdè Yorùbá sílẹ̀ ka má bàá fi ‘ÒJÓ’ pe ‘ÒJÒ’.

Álífábẹ́tì márùndínlọ́gbọ̀n ló wà nínú èdè Yorùbá, nínú àwọn álífábẹ́tì yí lati rí fáwẹ́lì méje tí méjìdílógún tó kù jẹ́ kọ́nsónántì. Kọ́nsónántì, fáwẹ́lì àti àmì ohùn ni ó pa pọ̀ tí èdè Yorùbá fi ṣe é sọ, tí ó sì dùn létí.

ÁFÁBẸ́tì YORÙBÁ:
A B D E Ẹ F G GB H I J K L M N O Ọ P R S Ṣ T U W Y.

FÁWẸ́lì YORÙBÁ:
A E Ẹ I O Ọ U.

KỌ́NSÓNÁNTÌ YORÙBÁ:
B D F G GB H J K L M N P R S Ṣ T W Y.

ÀMÌ-OHÙN:
DÒ ( ` )
RE ( - ) *a lè má fi ǹkankan sórí ọ̀rọ̀ náà.
MÍ ( ´ )

ÈTÒ TÍ À Ń GBÀ KỌ ÈDÈ YORÙBÁ

Gbogbo èdè ló ní bí wọ́n ṣe ń kọ ọ́ tàbí sọ ọ́. Èdè kan ò ju ìkan lọ, wọ́n sì yàtọ̀ sì’ra wọn. Ìlànà kíkọ èdè Yorùbá ni:

1.     A ti sọ ṣájú pé kọ́nsónántì, fáwẹ́lì àti àmì-ohùn ni ó jẹ́ kí èdè Yorùbá dùn-ún sọ.
2.     Èyí-kéyìí nínú kọ́nsónántì tàbí fáwẹ́lì ló lè bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ Yorùbá, àmọ́, fáwẹ́lì nìkan ló lè parí ẹ̀. Èyí ni pé, kọ́nsónántì kìí parí tàbí gbẹ̀yìn nínú ọ̀rọ̀ Yorùbá.
3.     Kọ́nsónántì kìí tẹ̀lé arawọn nínú ọ̀rọ̀ Yorùbá. Èyí ni pé a ò lè rí nǹkan bíi sh* nínú èdè Yorùbá.
4.     Àmì orí ọ̀rọ̀ ṣe pàtàkì. Èyí ni láti jẹ́ kó ṣe é kà, fi ìyàtọ̀ hàn nínú ọ̀rọ̀ (ìtumọ̀).
5.     Fáwẹ́lì àti kọ́nsónántì “M àti N” nìkan ló lè ní àmì-ohùn lórí.

Ẹ ṣé fún àkókò yín, èdè Yorùbá ò ní parun (Àṣẹ). Ẹ kọ èro yín sí ìsàlẹ̀ nítorí ó ṣe pàtàkì sí wa.

No comments:

Post a Comment