Gbajúgbajà olórin, Dáre Art Àlàdé ti ṣàlàyé àṣírí ohun tí
ó so òun àti ìyàwó ẹ̀ Déọlá pọ̀. Ó ti tó ọdún mẹ́wàá tí wọ́n ti fẹ́ra, wọ́n bí ọmọ
méjì.
Darey sọ pé àìmú nǹkan le àti ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ni ó ṣe
kókó. Àtipé lílo àkókò pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí.
Ó ní nínu gbogbo ohun tí òun ṣe, òun ma ń fi ẹbí ṣájú. Ó
sọ síwájú si pé kò sí ẹni tó mọ́, kò sì sí ìdílé tí kìí jà. Ọgbọ́n tí a ma fi
borí ìjà náà ló jù. Àṣírí míràn ni pé òun kìí sọ̀rọ̀ jù, ìgbéyàwó òun ò sí fún
aráyé.
Ó ní bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpèníjà wà nínú ìgbeyàwó, ìpinu ọkàn
láti dúró nínú ẹ̀ ló ṣe kókó.

No comments:
Post a Comment