Ní ìdíje Premier League, ìfagagbága méje ló wáyé. Nínú
méje, àwọn mẹ́rin nọrawọn, mẹ́ta síì gbá ọ̀mì.
Swansea na Liverpool mọ́’le pẹ̀lú ayò mẹ́ta sí méjì.
Llorente ló gbá ayò méjì wọ’lé fún Swansea tí G. Sigurdsson si fadé le. Roberto
Firmino ló gbá ayò méjì wọlé fún Liverpool tí ìyà náà ò fi dùn wọ́n.
AFC Bournemouth wọ̀dí ìjà pẹ̀lú Watford. Àwọn méjéèjì gbá
ọ̀mì. J. King àti B. Afobe ló gbá ayò wọlé fún Bournmouth, C. Kabasele àti T.
Deenay ló gbá ayò fún Watford.
S. Coleman ló la ìjà láàárín Crystal Palace àti Eẹerton.
Ayò kan tí Coleman gbá ni Crystal Palace fi jáwé olúborí.
WestHam United na Middlesbrough ní ayò mẹ́ta sí ìkan.A.
Carroll àti J. Calleri ni ó bá WestHam gbá ayò mẹ́ta náà, Carroll gbá méjì,
Calleri sí gbàá ìkan wọlé. C. Stuani ló bá Middlesbrough dá ayò kan padà tí ìyà
náà ò fi pọ̀jù.
Manchester United ò gbà fún Stoke City, wọ́n jọ gbá ọ̀mì
ayò. Mata ló kọ́kọ́ gbá ayò wọlé fún Stoke City kí Wayne Rooney tó wá bá Man.
United dá ẹyọkan náà padà.
WestBromuich Albion fojú Sunderland gbolẹ̀ pẹ̀lú ayó méjì
s’ódo. D. Fletcher àti C. Brunt ni ó pín ayò náà láàárín arawọn eléyìí ló mú àwọn
ẹgbẹ́ agbá-bọ́ọ̀lù Sunderland àti alátìlẹyìn wọn jẹ túwó sùn.
Manchester City àti Tottenham Hotspur gbá ọ̀mì. Àwọn agbá-bọ́ọ̀lù
wọn ló pín ayò náà láàárín arawọn. L. Sane àti K. Bruyne ló bá Man. City gbá
ayò wọlé Tottenham, B. Alli àti Heung-Min Son bá Tottenham da padà.
Ní ìdíje ife-ẹ̀yẹ tilẹ̀ adúláwọ̀, ìfagagbága méjì ló wáyé. Àwọn agbá-bọ́ọ̀lù torílẹ́ èdè Ghana dojúkọ torílẹ̀ èdè Mali, àwọn agbá-bọ́ọ̀lù orílẹ̀ èdè Egypt nọ tán bí owó pẹ̀lú torílẹ̀ èdè Uganda.
Ghana na Mali, ayò kan sí òdo, èyí tí A. Gyan báwọn gbá wọlé.
Egypt àti Uganda gbá ọ̀mì òdo s’ódo.
No comments:
Post a Comment