Showing posts with label Yoruba news. Show all posts
Showing posts with label Yoruba news. Show all posts

Saturday, March 24, 2018

Aare Buhari: MÀÁ FÌYÀ JẸ OLÓRÍ ALÁÀBÒ TÍ ÌJÍNIGBÉ BÁ TÙN ṢẸLẸ̀.




Aare Muhammadu Buhari ti kede pe oun yoo ṣe iyemeji lati jẹbi awọn alabojuto aabo nigbati eyikeyi igbasilẹ ti gba silẹ ni eyikeyi apakan ti orilẹ-ede naa.
O sọ pe o ti paṣẹ fun wọn lati mu aabo ni ayika gbogbo ile-iwe.
O tun kilọ fun awọn ti o ṣalaye bi awọn ọrọ "iṣeduro", ni wi pe awọn alabojuto naa yoo "ṣe abojuto" wọn.
Buhari ṣe awọn ọrọ naa ni Ọjọ Jimo ni akoko gbigba ti o waye fun awọn ọmọbirin Dapchi ti o da silẹ ati awọn obi wọn ni Ile-Ile Presidential, Abuja.
Aare naa sọ pe, "Awọn iṣẹ aabo ni a ti ni iṣeduro lati fi awọn ilana siwaju sii ni ayika gbogbo awọn ile-iwe jẹ ipalara si awọn ipọnju lati rii daju aabo wa fun awọn ọmọ-iwe / awọn ọmọ-iwe ati awọn olukọ ati awọn ile-iwe.
"Mo ti gbe gbogbo awọn ile aabo mọ lati ṣiṣẹ lati rii daju pe a ko jẹri eyikeyi iyipada iṣẹlẹ wọnyi.
"Awọn olori alabojuto ti wa ni ikilo ni awọn alaye ti o peye pe eyikeyi ti o wa lori awọn ẹya wọn ni a yoo wo ni iṣaro," o wi.


 Niti awọn ti o peka si "iṣeduro ipo aabo ni orilẹ-ede", Buhari rọ wọn pe ki wọn "dawọ tabi koju awọn ile-iṣẹ aabo."
"Mo tun le ṣe ikilọ lodi si awọn ohun elo ti o ti yan lati ṣe idibajẹ ilu ti ipalara ti ilu wa.
"Ijọba yoo ko fi aaye gba igbiyanju eyikeyi eniyan tabi ẹgbẹ kan lati ṣe idiwọn tabi ṣe ẹtọ si awọn ẹtọ aabo fun awọn opin iṣoro ti iṣaju.
"Gegebi, awọn ile-iṣẹ aabo ko ni iyemeji lati ṣe ifojusi pẹlu awọn iru ọrọ irufẹ bẹ," o wi.

Thursday, January 26, 2017

ỌKỌ TÓ Ń YAN ÀLÈ TÀBÍ ÈYÍ TÓ Ń LU OBÌNRIN – ÌYÁBỌ̀ ÒJÓ




Ògbóntarìgì òṣèré obìnrin, Ìyábọ̀ Òjó ti gba àwọn obìrin níyànjú irúfẹ́ ọkọ tó dáa ju láàárín èyí tó ń yan-àlè àti èyí tó ń lu ìyàwó ẹ̀. Ìyábọ̀ Òjó ń fi irúfẹ́ àwọn ọkùnrin bàyìí wéra, ó jẹ́ ka mọ̀ pé ìkan san ju ìkejì lọ.

Ó jẹ́ ka mọ̀ pé àwọn ọkùnrin tó ń yan-àlè sàn tí irúfẹ́ ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ò bá ṣe é délé. Ó ní ohun kan tí ọkùnrin tó ń lu ìyàwó fẹ́ ni kí inú ìyàwó náà má dùn èyí tí kò dára fún obìnrin.

Ó ní tí ọkùnrin bá wà tó ń tọ́jú ẹbí ẹ̀ tó wá ń ṣe ṣìná níta, irúfẹ́ ọkùnrin bẹ ṣì ṣeé bá gbélé. Ṣùgbọ́n tí ọkọ bà fi ojoójúmọ́ na ìyàwó ẹ̀, tí ìyàwó náà sì ń paá mọ́ra àfàìmọ̀ kó má jẹ̀ẹ́ ikú ló ń bò mọ́ra.


Ìyábọ̀ Òjó ló ń dá tọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ méjì, Festus àti Priscilla làti bí ọdún mẹ́wàá báyìí. Ó dáwa lójú pé ó mọ ohun tó ń sọ.

OHUN TÓ FA ÀÌRÓJÚ NÍNÚ ÌGBEYÀWÓ TONTO DIKEH - ỌMỌ Ọ̀DỌ̀



Láti bí ọjọ́ díẹ̀ sẹ́yìn ni ìròyìn ti ń gbe pé ó ṣeéṣe ki ìgbeyàwó Tonto Dikeh àti Ọlákúnlé dàrú nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ tó ń fì wọ́n.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ri kà ní entertainment.naij, ìkan lára ọmọ ọ̀dọ̀ ẹ̀ ló sọ pé Tonto Dikeh ti padà sí ìgbé-ayé ẹ̀ tẹ́lẹ̀. Ìgbé-ayée lílo ògùn olóró, èyí tó ma ń jẹ́ kó ṣìwàwù. Ìwà tó ń wù yì ló mú ọkọ ẹ̀ Ọlákúlé Ọládùnní rìnìn àjò lọ Ghana bóyá kí òun tó dé ó lè ti yípadà.

Ọmọ ọ̀dọ̀ náà sọ pé nítorí ògùn olóró yìí, Tonto Dikeh ma ń ba nǹkan jẹ́ nílé. Ó ní ó ti ti ìyá ọkọ ẹ̀ ṣubú rí nígbàtí ó wá fún ilé ṣíṣí.

Ṣe bí a mọ̀ pé ìròyìn òkèrè bí ò lékan, á díkan. Ẹ jẹ́ ka ṣe sùúrù ka ma retí láti ẹnu Tonto fúnra ẹ̀ nítorí ẹnu oníkàn latí ń gbọ́ pọ̀un.

ÀṢÍRÍ ÌGBÉYÀWÓ ỌDÚN MẸ́WÀÁ MI – Darey



Gbajúgbajà olórin, Dáre Art Àlàdé ti ṣàlàyé àṣírí ohun tí ó so òun àti ìyàwó ẹ̀ Déọlá pọ̀. Ó ti tó ọdún mẹ́wàá tí wọ́n ti fẹ́ra, wọ́n bí ọmọ méjì.

Darey sọ pé àìmú nǹkan le àti ore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ni ó ṣe kókó. Àtipé lílo àkókò pẹ̀lú àwọn mọ̀lẹ́bí. Ó ní nínu gbogbo ohun tí òun ṣe, òun ma ń fi ẹbí ṣájú. Ó sọ síwájú si pé kò sí ẹni tó mọ́, kò sì sí ìdílé tí kìí jà. Ọgbọ́n tí a ma fi borí ìjà náà ló jù. Àṣírí míràn ni pé òun kìí sọ̀rọ̀ jù, ìgbéyàwó òun ò sí fún aráyé.

Ó ní bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìpèníjà wà nínú ìgbeyàwó, ìpinu ọkàn láti dúró nínú ẹ̀ ló ṣe kókó.

Monday, January 23, 2017

ÀPÒ ÌRẸSÌ ÀWỌN TÍ BOKO HARAM SO DI ALÁÌNÍLÉ DI TÍTÀ



Àwọn mẹ́fà kan ni àjọ EFCC mú pé wípé wọ́n ta àpò ìrẹsì èyí tó wà fún àwọn tí BH lé nílé ní ìlú Maiduguri. Umar Ibrahim tó jẹ́ alábojútó ẹ̀ka ohun-ọ̀gbìn ní ìjọba ìbílẹ̀ Mafa ni ó ta àpò ìrẹsì ọgọ́rùn-ún mẹ́ta èyí tó wà fún àwọn tí Boko Haram sọ di aláìnílé ní ìjọba ìbílẹ̀ náà. Àwọn ‘Danish Refugee Councel’ (DRC) ló fi àwọn àpò ìrẹsì náà tawọ́n lọ́re.

Àwọn afunrasí tí wọ́n mú pẹ̀lú ọ̀gbẹ́ni Ibrahim ni; Bulama Ali Ṣangebe àti Modu Bulma tí ó jẹ́wọ́ pé alága ìbílẹ̀ ni ó sọpé kí àwọ́n ta àwọn àpò ìrẹsì náà. Wọ́n tàá fún ọ̀gbẹ́ni Umar Salisu, wọ́n ta àpò kànkan ni 8500*.

Saturday, January 21, 2017

ERÉ BỌ́Ọ̀LÙ TÓ WÁYÉ LÓNÌÍ







Ní ìdíje Premier League, ìfagagbága méje ló wáyé. Nínú méje, àwọn mẹ́rin nọrawọn, mẹ́ta síì gbá ọ̀mì.

Swansea na Liverpool mọ́’le pẹ̀lú ayò mẹ́ta sí méjì. Llorente ló gbá ayò méjì wọ’lé fún Swansea tí G. Sigurdsson si fadé le. Roberto Firmino ló gbá ayò méjì wọlé fún Liverpool tí ìyà náà ò fi dùn wọ́n.

AFC Bournemouth wọ̀dí ìjà pẹ̀lú Watford. Àwọn méjéèjì gbá ọ̀mì. J. King àti B. Afobe ló gbá ayò wọlé fún Bournmouth, C. Kabasele àti T. Deenay ló gbá ayò fún Watford.
S. Coleman ló la ìjà láàárín Crystal Palace àti Eẹerton. Ayò kan tí Coleman gbá ni Crystal Palace fi jáwé olúborí.

WestHam United na Middlesbrough ní ayò mẹ́ta sí ìkan.A. Carroll àti J. Calleri ni ó bá WestHam gbá ayò mẹ́ta náà, Carroll gbá méjì, Calleri sí gbàá ìkan wọlé. C. Stuani ló bá Middlesbrough dá ayò kan padà tí ìyà náà ò fi pọ̀jù.

Manchester United ò gbà fún Stoke City, wọ́n jọ gbá ọ̀mì ayò. Mata ló kọ́kọ́ gbá ayò wọlé fún Stoke City kí Wayne Rooney tó wá bá Man. United dá ẹyọkan náà padà.
WestBromuich Albion fojú Sunderland gbolẹ̀ pẹ̀lú ayó méjì s’ódo. D. Fletcher àti C. Brunt ni ó pín ayò náà láàárín arawọn eléyìí ló mú àwọn ẹgbẹ́ agbá-bọ́ọ̀lù Sunderland àti alátìlẹyìn wọn jẹ túwó sùn.

Manchester City àti Tottenham Hotspur gbá ọ̀mì. Àwọn agbá-bọ́ọ̀lù wọn ló pín ayò náà láàárín arawọn. L. Sane àti K. Bruyne ló bá Man. City gbá ayò wọlé Tottenham, B. Alli àti Heung-Min Son bá Tottenham da padà.





 
Ní ìdíje ife-ẹ̀yẹ tilẹ̀ adúláwọ̀, ìfagagbága méjì ló wáyé. Àwọn agbá-bọ́ọ̀lù torílẹ́ èdè Ghana dojúkọ torílẹ̀ èdè Mali, àwọn agbá-bọ́ọ̀lù orílẹ̀ èdè Egypt nọ tán bí owó pẹ̀lú torílẹ̀ èdè Uganda.

Ghana na Mali, ayò kan sí òdo, èyí tí A. Gyan báwọn gbá wọlé. Egypt àti Uganda gbá ọ̀mì òdo s’ódo.