Showing posts with label Iyabo Ojo. Show all posts
Showing posts with label Iyabo Ojo. Show all posts

Thursday, January 26, 2017

ỌKỌ TÓ Ń YAN ÀLÈ TÀBÍ ÈYÍ TÓ Ń LU OBÌNRIN – ÌYÁBỌ̀ ÒJÓ




Ògbóntarìgì òṣèré obìnrin, Ìyábọ̀ Òjó ti gba àwọn obìrin níyànjú irúfẹ́ ọkọ tó dáa ju láàárín èyí tó ń yan-àlè àti èyí tó ń lu ìyàwó ẹ̀. Ìyábọ̀ Òjó ń fi irúfẹ́ àwọn ọkùnrin bàyìí wéra, ó jẹ́ ka mọ̀ pé ìkan san ju ìkejì lọ.

Ó jẹ́ ka mọ̀ pé àwọn ọkùnrin tó ń yan-àlè sàn tí irúfẹ́ ọkùnrin bẹ́ẹ̀ ò bá ṣe é délé. Ó ní ohun kan tí ọkùnrin tó ń lu ìyàwó fẹ́ ni kí inú ìyàwó náà má dùn èyí tí kò dára fún obìnrin.

Ó ní tí ọkùnrin bá wà tó ń tọ́jú ẹbí ẹ̀ tó wá ń ṣe ṣìná níta, irúfẹ́ ọkùnrin bẹ ṣì ṣeé bá gbélé. Ṣùgbọ́n tí ọkọ bà fi ojoójúmọ́ na ìyàwó ẹ̀, tí ìyàwó náà sì ń paá mọ́ra àfàìmọ̀ kó má jẹ̀ẹ́ ikú ló ń bò mọ́ra.


Ìyábọ̀ Òjó ló ń dá tọ́ àwọn ọmọ ẹ̀ méjì, Festus àti Priscilla làti bí ọdún mẹ́wàá báyìí. Ó dáwa lójú pé ó mọ ohun tó ń sọ.