Monday, January 23, 2017

ỌKỌ̀ BÀLÚÙ OLÓGUN JU ÀDÁN-OLÓRÓ....



Lọ́jọ́ ìṣẹ́gun ọ̀sẹ̀ yí, ọkọ̀ bàlúù ológun ju àdán-olóró sí ibi tí wọ́n kó àwọn tí Boko Haram (BH) lé kúrò ní ilé wọn. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yí àwọn èèyàn ọgọ́rùn-ún ni ló tẹ́rí-gbaṣọ, tí ọ̀pọ̀ èèyàn si farapa. 

MG Lucky Irabor sọ pé àwọn gbọ́ pé BH tuń-ún gbárajọ ní ìjọba ìbílẹ̀ Kala Balge ni Borno. Èyí ló fàá tí àwọn ọmọ-ogun òfurufú fi gbéra lọ láti kojú wọn àmọ́ ó ṣeni láàánú pé ibi tí wọ́n kó àwọn tí BH lé kúrò nílé gangan ni wọ́n ju àdán olóró náà sí. 

Ẹgbẹ́ Red Cross àgbáyé ti ṣe ìrànwọ́ fún àwọn tó farapa láti rí pé wọn de ilé-ìwòsàn láti gba ìtọ́jú. Isa Gusau tó jẹ́ agbẹnusọ fún Gómínà Borno sọ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà jẹ́ ohun tó bani lọ́kàn jẹ́ àtipé àwọn ti ń sètò láti ri pé ìtójú wà fún àwọn tó farapa. Ó jẹ́rìí si pé àwọn ẹgbẹ́ Red Cross àgbáyé ti ń ṣè’rànwọ́ fún àwọn tó farapa. Ó sọ síwájú pé mínísítà fún ètò ìlera ti kàn sí àwọn òṣìṣẹ́ ìlera làti ri pé àwọn tó farapa ma rí ìtọ́jú lẹ́sẹ̀-kẹsẹ̀ tí wọ́n bá gbé wọn dé ilé-èwòsàn ni Maiduguri.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti fẹnu tẹ́mbẹ́lú ìṣẹ̀lẹ̀ náà, tí wọ́n sì rọ ìjọba kí wọ́n wádìí ohun tó fàá tí àwọn ológun ṣe fi BH sílẹ̀ lọ dojúkọ àwọn tí BH ṣọṣẹ́ fún.

Ìròyìn tí a tún gbọ́ ni pé ó dàbí pé àwọn ológun òfurufú mọ̀ọ́mọ̀ ni. Ọ̀gbẹ́ni  Abdulwahab Adam tí ó wà níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà sọ pé àdán olóró tí wọ́n jù tó mẹ́ta, ó ní ẹ̀mẹta ti kúrò ní àṣìṣe. Ẹlòmíràn, ọ̀gbẹ́ni Abba Yusuf sọ pé ó le láti gbàgbọ́ pé wọn ṣèèṣì nítorí àgọ́ tí wọ́n ju àdán olóró sí kìí ṣe tuntun, àtipé ó ṣe pé ìgbàtí àwọn ń tò fún nǹkan ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. 

SOURCES: anguard, Saharareporters, Pulse

No comments:

Post a Comment