Monday, January 23, 2017

AÀRẸ GBÀYÈ ỌJỌ́ MẸ́WÁÀ




Lọ́jọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀ yí, Aàrẹ Mohammed Buhari kọ̀wé sí sẹ́nátì fún àyè ọlọ́jọ́ mẹ́wàá gbáko. Gẹ́gé bí a ṣe kàá ní SAHARAREPORTERS, àwọn sẹ́nétì ka lẹ́tà náà nígbàtí wọ́n jòkó. Nínú lẹ́tà náà ni Aàrẹ ti sọ pé òun nílò ọjọ́ mẹ́wàá nítorí ìlera ara èyí tó fi igbákejì sí ipò olùṣàkóso orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ajé, ọjọ́ kẹtàlélógún ni lẹ́tà náà sọ pé Aàrẹ Mohammed Buhari ma bẹ̀rẹ̀ ìsinmi náà àmọ́ ọjọ́ kankàndínlógún ni wọ́n gbéra lọ sí orílẹ̀-èdè United Kingdom láti gba ìtọ́jú tó péye.

SOURCE: saharareporters

No comments:

Post a Comment