Òjíṣẹ́ Ọlọ́run ti ìjọ Ìràpadà t’Ọlọ́run (RCCG), Alex Ochienu ló sọ bí ológun méjì ṣe na òun títí t’óùn fi
dákú nítorí wọ́n ní kí òun fa etí, kí óun sì ma kúrú-ga. Éyí tí òun kọ láti ṣe.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí òjíṣẹ́ Ọlọ́run náà sọ, Cpl. M. Dankwa ló kọ́kọ́ nàá kí
ológun kejì tí kò mọ orúkọ ẹ̀ to fọwọ́ kun. Ó sọ síwájú si pé wọ́n na òun tí
òun sì dákú. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn tó wà nítòsí ló gbé òun lọ sí ilé-ìwòsàn tìjọba tó
wà ní Gwarimpa ni Abuja.