Èyí ni láti kí i yín káàbọ̀ sí ‘Yorùbá Online News’, ibi
tí ẹ̀ ti ma gbádùn kíka ìròyìn lédè Yorùbá. A ti pinu láti ma mú ìròyìn wa fún
kíkà yín, ìròyìn nípa ètò-òṣèlú, eré-ìdárayá, òwò, àwon olórin àti òṣèré, àti bẹ́ẹ̀
bẹ́ẹ̀ lọ.
A ri pé ó tó àkókò láti gbé èdè Yorùbá ga nípasè ìròyìn ṣíṣe.
A mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ló ti bẹ̀rẹ̀ irúfẹ́ ohun báyìí àmọ́ wọn ò ní àǹfàní láti tẹ̀síwájú
nítorí ìdí kan tàbí òmírán. Àwá kán lùú nítorí ìfẹ́ ta ní sí èdè Yorùbá àti ìfẹ́
jíjẹ́ kí àwọn èyàn mọ ohun tó ń lọ ní àyíká wọn.
Gbogbo ohun tó jẹ́ kí àwọn aṣájú má lè tẹ̀síwájú lati fi
sọ́kàn, èyí ló jẹ́ ka pinu pé:
1.
Gbogbo
ohun tí àwọn elédè Gẹ̀ẹ́sì bá kọ lórí ìròyìn kan ni a ma pòpọ̀ ta ma kọ fún
kíkà yin-ín lédè Yorùbá. Èyí ni láti dín iṣẹ́ ògbúfọ ṣíṣe kù àti láti jẹ́ kẹ mọ
òye òótọ́ ìròyìn náà.
2.
Èdè
Yorùbá àjùmọ̀lò ni a ma fi kọ ìròyìn, ẹ foríjì wá tí èdè àyálò bá pọ̀jù.
3.
Bí
ìròyìn náà ṣe ń jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì, a ma sa ipa àti agbára wa láti ri pé ìròyìn
náà kò pẹ́ kàn yín lára.
4.
A
ma nílò èrò yin nítorí igi kan kò lè dágbó ṣe, àjèjì ọwọ́ kan ò gbẹ́rù dórí.
Ka tó bẹ́ lu agbami ìròyìn, a ma sọ nípa èdè Yorùbá àti
òǹkà Yorùbá.
Ẹ sẹ́ tí ẹ darapọ̀ mọ́ wa, ẹ m báwa ká lọ. Àjọṣepọ̀ o nì
bàjẹ́ (Áṣẹ). Ẹ ò ní wá wa tì (Áṣẹ)
Ẹ MA BÁWA KÁ LỌ!!!