Wednesday, November 29, 2017

WỌN PAṢẸ FUN AWỌN OLOGUN LATI KỌ EDE IGBO, HAUSA ATI YORUBA.

.




Aṣẹ ti wa fun awọn ọmọ-ologun orilẹ-ede Naijiria ki wọn kọ ede igbo, Hausa ati Yoruba ki ọdun 2019 to wọle de.Agbẹnusọ awọn ologun, Usaman Sani lo sọ eyi di mimọ ni ọjọru pe idi ti wọn fi gbe eto yi jade ni pe o ma jẹ ki awọn ọmọ-ologun orilẹ-ede Naijiria le sọ awọn ede mẹta to ṣe pataki lorilẹ ede naa. Atipe ti rogbodiyan ba ṣẹlẹ, ko ni nira fun ologun kan kan lati le ba awọn ara adugbo naa sọrọ.

Wọn sọ siwaju si pe awọn to ba fẹ darapọ mọ awọn ọmọ ologun nisinyin, mimọ ede Hausa, igbo ati Yoruba  ma jẹ anfani pataki. Ko to di igbayi, wọn ti rọ awọn ọmọ ologun orilẹ-ede Naijiria lati mọ ede Faranse, Arabiki ati bẹẹ bẹẹ lọ.

No comments:

Post a Comment