Wednesday, November 8, 2017

IPÒ ÌLERA HALIMA ABUBAKAR.






Òṣèré lágbo àwọn elédè gẹ̀ẹ́sì, Halima Abubakar ni ìròyìn jẹyọ lọ́jọ́ díè sẹ́yìn pé ara ẹ̀ kò yá. Akẹgbẹ́ ẹ̀ lágbo òṣèré, Tonto Dikeh ni ó lọ gbe ní iléèwòsàn.

Ìròyìn ta gbọ́ ni pé àrùn iju ló ń ba jà. Lọ́wọ́ báyìí, ó ti ń padà bọ̀ sípò. Èyí la rí kà lórí ẹ̀rọ-alátagbà oṣèré nà, àbúrò ẹ̀ ló fi dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn tó dúró tìí, àwọn olólùfẹ́ ẹ̀ pẹ̀lú aláànú ẹ̀ bí i ìyàwó Gómínà ìpínlẹ̀ Kogi.

Òṣèré nà fúnra ẹ̀ kí akẹgbẹ́ ẹ̀, Uche Elendu kú ọjọ́ ìbí. Èyí tó fihàn pé àláfíà ti ń déba.

No comments:

Post a Comment