Iroyin to n
tẹ wa lọwọ bayi nipe ijọba orilẹ-ede Naijiria ti pese owo ajẹmọnu fun awọn to n
ko ounjẹ ati awọn nnkan meremere lo si oke-okun. Ijọba apapọ pinu lati ṣe eyi
ki iwuri ba le wa fun awọn to n ko nnkan lọ si oke-okun.
Nibi ipade awọn agbẹ ti ilu Eko ni a ti ri eyi gbo. Wọn sọ
siwaju pe fun gbogbo nnkan ti ile-iṣẹ abi eeyan kan ba ko lọ si oke-okun, ijọba
apapọ orilẹ-ede Naijiria ti ṣetanlati san ìdá owo ti ile-iọẹ tabi ẹni na ri ki
o jẹ ajẹmọnu ẹ. Wọn ni fun awọn to ti n ko nnkan lọ si ilẹ okere tẹlẹ, wọn ma
fun wọn ni ida-marun (5%) iye ohun ti wọn ko lọ si oke-okun ti awọn to jẹ igba
akọkọ wọn awọn ma fun ni ida-marundinlogun (15%) iye ohun ti wọn ko lọ
oke-okun.
Eyi ni pe ti ẹni to ti n ko ọja lọ si oke okun ba ko ọja
miliọnu marun naira lọ si oke-okun, ijọba orilẹ-ede Naijiria ma fun ni 500,000.
Ti ẹni to ṣẹṣẹ bẹrẹ ba ko iye ọja kan naa lọ, o ma gba
Awọn ohun ti wọn ma bere fun nibi eeyan ma ti gba owo naa ni; awọn iwe ti o
fi ko ọja naa lọ oke-okun, iwe owo-ori, awọn iwe ile-iṣẹ. Wọn ni ki eeyan kan
si ajọ to n ri si gbigbe nnkan lọ si oke-okun; Nigeria Export Council
Commission (NECC).
No comments:
Post a Comment