Ìjọba Èkó ti
jẹ́ka mọ̀ láti ẹnu igbákejì Gómínà Arábìnrin Idiat Adébùle tó tún jẹ́ ẹni tó ń
mójútó ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́ ní ìpínlẹ̀ náà pé kò ní sí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní àkókó ìsinmi
gbọrọ nítorí ètò àbò. Èyí jẹyọ nínú ìwé tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí àwọn akọ̀wé ẹ̀ka
ètò ẹ̀kọ́ ni agbègbè mẹ́fà ìpínlẹ̀ Èkó.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́
yí ló yẹ kó wáyé láti ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣùn yí di ọjọ́ karùnlélógún oṣùn kẹjọ.
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ yí wà fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ sẹ́kọ́ndírì
tó nífẹ̀ sí ìmọ̀ sáyẹ́nsì. Wọ́n fagile torí bí ìṣọwọ́ jínigbé ṣe pọ̀ si àti
pàápàá jùlọ àwọn ọmọ ilé-ìwé mẹ́fà tí wọ́n jígbé ní Igbónlá lẸ́pẹ̀ẹ́ tí wọn kò
tí ì rí gbà padà. Àwọn ọmọ mẹ́fà nàá ni; Isiaq Rahmon, Peter Jonah, Farouq
Yusuf, Pelumi Philips, Judah Agbausi ati Adebayo George.
Ó ti tó ọjọ́
mẹ́rìnléláàdọ́ta tí àwọn gbọ́mọ gbọ́mọ náà ti ṣèlérí pé wọ́n má fi àwọn ọmọ náà
sílẹ̀ àmọ́ a ó rómira, a ó rẹ́jẹ̀-ara.
No comments:
Post a Comment