Wednesday, November 15, 2017

LAKE RICE ṢI N TA WARA WARA.






Lẹyin awuyewuye pe igba ọdun  nikan ni ijọba ipinlẹ Eko ma n ta irẹsi ti wọn fọwọsowọpọ pẹlu ipinlẹ Kebbi ṣe ti a mọ si ‘Lake rice’ ni gomina Akinwunmi mbọde ti ṣe ikede pe awọn irẹsi naa ti wa ni awọn ibi ti wọn ti n ta atipe gbogbo eeyan lo wa fun.
Ninu ikede ti kọmiṣọna fun ọgbin, Ọnọrebu Oluwatoyin Suarau sọ leni fun awọn oniroyin ni Alausa pe ijọba ipinlẹ Eko ti pese ibi ti a ti le ri irẹsi naa ra yatọ si ile ijọba ibilẹ ogun ati LCDA to wa ni ipinlẹ Eko ti a ti n ra a tẹlẹ. Awọn ibi ti a ti le ri ra naa ni; Fish Farm Estate ni Odogunyan ni Ikorodu; Farmers Mart, Surulere; Agric Input Supply Authority (LAISA), Ojo; Agricultural Development Authority (ADA), Oko-ọba, Agege ati Lagos Teleẹision (LTV), Ikeja.

Ọgbẹni Suarau sọ pe ijọba ipinlẹ Eko n ṣiṣẹ takun takun lati ri pe irẹsi naa wa kaakakiri gbogbo ibi ti wọn ti darukọ loorekore atipe iye ti wọn ta irẹsi naa ko tii yi pada nitori ijọba fẹ ki gbogbo eeyan ipinlẹ Eko ri ra ni owo pọku.


No comments:

Post a Comment