Ọkan lara awọn
aṣa ilẹ Yoruba ti igbalode ti gba lọwọ wa ni irẹmọlẹkun (rirẹ ọmọ lẹkun), eyi
ni pipẹtu si inu ọmọ to ba n sunkun agaga ọmọ ọwọ. O ṣẹni laaanu pe aṣa yi wa
lara awọn aṣa to ti n di igbagbe nitori ọlaju. Ni ode oni, ọpọ iya la ma roju
koko ni kete ti ọmọ wọn ba n sunkun, omiran a ma bere lọwọ ọmọ ti ko mọ nkan pe
‘ṣe bi o ṣẹ jẹun tan ni?’, ọpọ a ti ẹ ma bi ọmọ naa ohun to n ṣe bii ki ọmọ da
lohun. Ọpọ nnkan ni ọmọ to n sunkun le fẹ; bii ki ebi ma pa, ko fẹ sun ati bẹẹ
bẹẹ lọ.
Irẹmọlẹkun jẹ
ọna kan gboogi lati jẹ ki ọmọ dakẹ igbe, ọpọlọpọ igba si ni wọn maa n lo o lati
jẹ ki ọmọsun-un. Ọna meji la le gba rẹ ọmọ lẹkun; Oriki ati Orin. Awọn ọna meji
yi lo maa n ṣiṣẹ bi idan.
Oriki ni ilẹ
Yoruba wulo fun ọpọlọpọ nnkan, lara wọn ni irẹmọlẹkun. Oriki le jẹ ti idile
(baba tabi iya) abi orukọ amutẹrunwa ( aina, ojo, ige...). Ti ọmọ ba n sunkun,
ti iya ẹ si ran oriki ẹ lẹnu o di dandan ki o dakẹ igbe to ba jẹ olori gaari.
Amọ iya melo lo mọ oriki idile ka to wa so oriki orukọ amutọrun wa.
Awọn orin ti
a n lo lati rẹmọlẹkun nilẹ Yoruba pọ jantirẹrẹ, awọn orin yi maa n ni anfani
lori awọn ọmọ yatọ si ki wọn dakẹ igbe.Ta ba tẹti si awọn orin irẹmọlẹkun
daadaa a ma ṣakiyesi pe o kun fun iwure, ko si si ọrọ odi ninu ẹ rara. Apẹẹrẹ
ni;
Ta lo naa o
Ẹyẹ ni o
Soko ba o,
Ko salọ o.
Jide nkọ o,
O wa nile o
Ki lo n ṣe o
O n kọle lọ
wọ
O n ralẹ lọwọ
Ile alaja
melo?
Ile alaja mẹta
O kọ ikan
fun mama,
O kọ ikan
fun baba,
Oun na mu ri
ẹ,
Ẹ le jẹ ka mọ
orin irẹmọlẹkun tẹ mọ...
No comments:
Post a Comment