Wednesday, November 15, 2017

AGBEKALẸ ẸGBẸ ALAGBỌN NI IPINLẸ EKO






Ni anọ ni ipinlẹ Eko ni a ṣe agbekalẹ ẹgbẹ awọn alagbọn. Awọn wọnyi ni ijọba ipinlẹ Eko damọ gẹgẹ bi ẹni to n gbin ati to n sọ agbọn di ohun-elo. Inu agbala ‘Agric Deẹelopment Project’ ni ayẹyẹ naa ti waye ti awọn eeyan jankan-jankan ni eto agbẹ o gbẹyin nibẹ. Lara awọn to wa fun igbekalẹ naa ni; Ọtunba Fẹmi Oke to jẹ alaga ẹgbẹ awọn agbẹ ni ipinlẹ Eko, Hon. Ganiu Sanni to jẹ olubadamọran si gomina ipinlẹ Eko nipa ohun ọgbin, Alhaji Mohammed Mustapha to jẹ alaga fun awọn alagbọn, Arabinrin Tokunbọ, Ọgbẹni Ọlawale Ọnasanya.

Ninu ọrọ iṣide ọgbẹni Ọnasanya, o jẹ ka mọ pe ọdun 2016 ni ijọba ipinlẹ Eko ti pese ilẹ fun awọn to nifẹsi lati gbin agbọn. O ni kii ṣe ilẹ nikan ni ijọba ipinlẹ eko fi ran wọn lọwọ, wọn pese awọn irin-iṣẹ igbalode ti wọn fi le ma sọ agbọn naa di awọn ohun-elo yatọ si pe a fẹ jẹ agbọn lasan. Lẹyin eyi ni alaga awọn agbẹ, Ọtunba fẹmi Oke sọ pe awọn ti n duro de iru anfani yi ọjọ pẹ amọ inu awọn dun nitori isinyi to de naa ko tii pẹ ju. O ni awọn ẹgbẹ agbẹ wa lẹyin wọn bi ike.

 Alhaji Mustapha wa dupẹ lọwọ gbogbo awọn ti wọn wa fi ijoko yẹ wọn si, o ni ẹgbẹ ti wọn gbe kalẹ yi wa fun gbogbo eeyan to nifẹsi ati maa gbin agbọn. Wọn ni eyi pese iṣẹ fun awọn ti ko ni nitori awọn eeyan kan lo n ba awọn ṣe irinṣẹ to n sọ agbọn di ohun-elo.

Alhaji Mustapha wa sọ siwaju awọn nnkan ti a le ri ninu agbọn bi, ororo, a le fi ṣe ọṣẹ, a le fi se ounjẹ, a le fi ṣe burẹdi ati bẹẹ bẹẹ lọ. O rọ awọn eniyan ki wọn darapọ mọ awọn atipe awọn ti wọn ba ni oko agbọn tẹlẹ naa le jẹ anfani eyi nipa gbigbe ohun ere oko wa si ọdọ wọn ni Ẹpẹ lati sọ di ohunkohun to ba wu.


No comments:

Post a Comment