Wednesday, November 15, 2017

IṢẸ́ ÀGBẸ̀ LÓRÍLẸ̀-ÈDÈ NÀÌJÍRÍÀ




 

“Iṣẹ agbẹ, niṣẹ ilẹ ẹ wa. Ẹni ko ṣiṣẹ, a ma jale. Iwe kikọ lai si ọkọ ati ada koi pe o, koi pe o.”

Yoruba bọ wọn ni, ‘odo to ba gbagbe orisun ẹ, o ma gbẹ ni’. Eyi lo difa fun eto owò orilẹ-ede Naijiria to n ji bọ diẹ diẹ nitori a pada si orisun eyi to jẹ AGBẸ. Tẹlẹ ri lorilẹ-ede Naijiria, iṣẹ agbẹ lo maa n mu owó wọle. Lati ori ẹpa de ori koko ati awọn ohun ọgbin miran ta n ko lọ si orilẹ-ede miran ni a ti ri owo ti a n naa gẹgẹ bi orilẹ-ede. Amọ lati igba ti a ti ri epo-rọbi, gbogbo nnkan yi pada. Nisinsin y ti owo epo rọbi o ka oju-ilu a ti n pada si iṣẹ agbẹ.

Ohun ayo ibẹ ni pe ijọba o le da a ṣe, eyi ni pe wọn fi aye gba aladani. Ohun miran to wa nibẹ nipe kii ṣe ohun agbẹ nikan ni wọn ri gẹgẹ bi ohun ọgbin, awọn ohun ọsin naa ni wọn ti gbe si abẹ agbẹ. Awọn ohun ọsin bii; ẹja, ẹlẹdẹ, adiyẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ. Awọn ohun ọsin yi ni wọn le ko lọ si oke-okun naa.

Gẹgẹ bi alakọwe to kawe gboye to n ro pe ‘ṣe emi ma gbe iwe-ẹri mi silẹ lati lọ ma tu oko ni?’ Eyi ko pọndandan, ti o ba ti ni lọkan pe oun fẹ ṣe agbẹ tabi ni ohun ọsin nnkan to ma ṣe ni lati gba eeyan sibẹ taa ma ba mojuto eyi ti oun naa yoo ma yọju si loorekoore. Eyi ni ọpọ eniyan nṣe nisinyi. O le pinu lati ko ere oko lọ si oke-okun tabi ta a si orilẹ-ede Naijiria.

Mi o ni owo lati bẹrẹ kan o si nibẹ, nitori lati ori ijọba apapọ titi de ori ijọba ibilẹ pẹlu awọn ile-ifowopamọ kankan ni wọn n gbe eto ẹyawo ati owo iranwọ silẹ fun awọn to ba fẹ da ile-iṣẹ silẹ paapaa awọn to fẹ bẹrẹ nnkan ọgbin. Lara awọn ajọ, eto ati ile-ifowopamọ to n ṣeranwọ fun agbẹ lorilẹ-ede Naijiria ni; FADAMA, BOI, BOA, LSETF, GTB, ile-ifowopamọ Diamond, ile-ifowopamọ agbaye (World bank).

Ẹ ma bawa kalọ nipa awọn eto ati iranwọ to wa fun agbẹ ninu iwe-iroyin wa ati ikanni.

No comments:

Post a Comment