Bo tilẹ jẹ pe ọpọ oṣiṣẹ ni ko fẹ fẹyinti, ti awọn omiran si n bẹru bi
igbe-aye wọn ṣe ma ri ti wọn ba fẹyinti lẹnu iṣẹ. Ba fẹ, ba kọ, ọjọ isinmi a
de. Ohun to tọna ka ṣe ni ka gbaradi fun nitori yoruba bọ wọn ni ‘ O n bọ, o n
bọ, awọn laa dẹ dee.’ Ti ọjọ-ori o ba fẹyin wa ti, iye ọdun ta lo lẹnu iṣẹ ma
fi eyin wa ti. Aitete feyinti awọn to ti dagba wa lara idi ti ko fi si iṣẹ lode
oni. Ọpọ to ti fẹyinti lo ni arun igba (stroke) nitori ara wọn ti yi mọ ki wọn
maa ṣiṣẹ.
Ọpọlọpọ lo fẹ
ba ile-iṣẹ ijọba ṣiṣẹ nitori owo ifẹyinti ti wọn ma gba amọ yatọ si ki owo wa
alpo, o ni awọn nkan ti agbọdọ ma ṣe ka ba le gbadun aye-ifẹyinti. Ohun akọkọ
fun awọn to ba n ṣiṣẹ aladani ni ki wọn ma da owo-ifẹyinti. Ọpọ ile-iṣẹ lo wa
ti o n gba owo ifeyinti.
Ohun miran
ti a le ma fi akoko wa ṣe ni ka lọ si agbo ariya tabi apejẹ. Ọpọ eniyan ni ko
ni akoko fun awọn mọlẹbi ẹ nigba ti o wa lẹnu iṣẹ. Akoko ifẹyinti jẹ igba ti a
le lo pẹlu awọn to sunmọ wa ki ẹlẹmi to de.
Ni akoko ifẹyinti,
a ni lati ma fi aye silẹ fun idaraya nitori ilera ara wa ṣe koko. Ka ma sai lọ
si ile-iwosan fun ayewo nitori ilera lọrọ. Aikiyesi ilera ara wọn ni ọpọ awọn
to ti fẹyinti ṣe ma n ni igba.
Ti owo ba
wa, a le da ajọ to n ran awọm alaini lọwọ silẹ tabi ka fi akoko wa fun ohun kan
ti a fẹ ki iyipada deba ni ayika tabi agbegbe wa. Eyi ma mu irẹwẹsi kuro ni ara
ati pe a jẹ ki ara wa ji pepe.
Ni akotan,
aififẹ han ati airi ẹni fẹ wa laraohun to n fa iku aitọjọ. Ka ri pe a ni eeyan
lọdọ tabi ka ko lọ si ọdọ awọn mọlẹbi ti wa ni tosi. Mo mọ pe oye eyi ni ọpọ afẹyinti
ṣe n lọ si ilu abinibi wọn ni kete ti wọn ba ti gba iwe ifẹyinti wọn.