Thursday, August 3, 2017

AGBA AKANṢẸ FẸYINTI








Wladimir Klitschko ti ṣe ọmọ orilẹ-ede Ukrain ni a gbọ pe o ti fẹyinti. Ti a o ba gbagbe Wladimir ni Anthony Joshua na ni oṣun kẹrin ọdun yi ti wọn si fẹ tun ija naa ja oṣun kọkanla. Amọ dede ni a gbọ ti o ṣe iroyin lori twitter pe oun fẹ fẹyinti.

Wladimir Klitschko ni o jẹ ẹni to mọ ẹṣẹ kan julọ ni gbogbo agbaye fun ọdun mẹwa ki Anthony Joshua to wa fi agba han. A ri ka pe ninu ija aadọrun o din ikan to ti ja ni gbogbo aye ẹ gẹgẹ bi akanṣẹ, Klitschko pegede ninu ọgọta o le mẹrin o si padanu marun pere. Iroyin jẹ ka mọ pe ifẹyinti to kede yi jẹ ko padanu owo rọgun rọgun ti iba gba ni oṣun kọkanla to ba jẹ pe o waye.

Ninu ikede ẹ, o dupẹ lọwọ ẹbi, ara ati ojulumọ ẹ. O ni o ṣoro ki oun ṣe ikede naa amọ bi oun ṣe rimọ gẹgẹ bi akanṣẹ niyi. O ni oun ṣi ni owo ti oun n ṣe. Ninu ọrọ alabojuto ẹ, o ni o ti pẹ ti Klitschko ti sọ fun oun, o dẹ ti de niyẹn. O ni oun ba gbero oriire ninu gbogbo oun to ba ma adawọle.

No comments:

Post a Comment