Tuesday, August 8, 2017

MAN’O WAR: KÍ Ẹ TÓ FÚN WỌN LÁṢẸ.






Ẹṣọ alabo pọ jantirẹrẹ ni orilẹ-ede Naijiiria, ohun to ṣeni laanu ni pe bi wọn ṣe pọ to naa ni iwa ibajẹ, ajẹgudujẹra ṣe pọ laarin wọn. Awọn ole ati ọbayejẹ naa o dinku lawujọ boya nipa aiṣiṣẹ wọn daada.

Ni ipinlẹ Eko nikan, a ni KAI (Kick Against Indiscipline); iyen awọn to maa n tapa si iwa idọta, LASTMA wa lati dari oju popo fun igboke-gbodo ọkọ. Pẹlu gbogbo awọn wọnyi, idọti ṣi pọ jantirẹrẹ lọna, awọn awakọ o fun LASTMA ni ọwọ kankan. Eyi jẹ ohun to buru ju.
Nnkan  to n sẹlẹ lọwọ bayi ni pe gbogbo ẹlẹṣọ-alabo ni riba ti wa ninu ẹjẹ wọn. Awọn ara-ilu ti sọ ni pa iwa adojuti  ni ti awọn ọlọpaa ma n wu gbogbo ẹnu ti bo tan. Awọn SARS naa nkọ? Ti wọn ma kan dede gbe ọdọ loju titi wipe ‘yahoo yahoo’ ni. Gbogbo eyi polukumṣu!

Iwa awọn MAN’O WAR ti wọn fi rọpo awọn ọlọpaa ni iyana-oriokuta lọna iṣawo nilu ikorodu lo n kan wa lomi inu. Wọn fi ọna silẹ, wọn n gbowo lọwọ awọn ọlọkada to n kọja ni opopona naa. Ọlọkada to ba kọ lati fun wọn ni owo rugi-oyin, wọn ma gba ọkada ni idi ẹ. Eyi mu mi duro woye pe ti awọn ile igbimọ-aṣofin ba wa fun wọn ni aṣẹ, ti wọn ro wọn lagbara nkọ? Mo ranti pe ajọ NSCDC naa wa ni iru ipo ti MAN’O WAR wa ki wọn to ro wọn lagbara.

Yatọ si iwa ibajẹ awọn MAN’O WAR  to n duro si orita yi, mo n ro nkan to ṣẹlẹ si awọn ọlọpaa to maa n duro sibẹ tẹlẹ to fi wa jẹ MAN’O WAR lo wa to n dari ọkọ abi LASTMA ti tan nilu Eko ni? O ma da ta ba ro o daadaa ka to ro wọn lagbara ati pe awọn to gba awọn ikọ MAN’O WAR to wa ni orita naa ba awọn eeyan wọn wi, ki wọn ti ọwọ agbejẹ wọn bọ aṣọ ki gudugbẹ to ja nitori to ba pẹ ti eeyan ti n le ẹranko to ba de ibi kan yoo maa koju si ẹni to n le.

No comments:

Post a Comment