Lati mu
idagbasoke ba owo to n wọle si ipinlẹ Kebbi, ijọba ipinlẹ naa fẹ ma ko ewurẹ lọ
si orilẹ-ede Saudi Arabia lojumọ. Wọn fẹ ṣe eyi pẹlu iranlọwọ Jaiz Bank.
Ẹni sọ eyi
di mimọ ni kọmiṣọna fun eto iṣuna-owo ipinlẹ Kebbi, Alhaji Jailari Muhammed
Yauri ni opin ọsẹ nigbati o n ba awọn akọroyin sọrọ pe awọn awọn ti ba Jaiz
bank sọrọ pe awọn le fun Saudi Arabia ni ewurẹ ẹgbẹrun meji nitori iye ti wọn
nilo lojumọ lọhun.
O sọ siwaju
pe awọn ba orilẹ-ede Niger Republic ati Benin Republic sọrọ pẹlu ajọṣepọ ipinlẹ
Sokoto ati Zamfara lati le ri ọwọ gbe lori owo agbẹ.

No comments:
Post a Comment