Gẹgẹ bi eto
iran ara-ilu lọwọ, ile-ifowopamọ Heritage ti fọwọsowọpọ pẹlu ijọba ipinlẹ Ọyọ
ni ṣiṣe atunṣe si eto ilera ipinlẹ naa
nipa gbigba aadọta biliọnu naira fun eto ilera ni ipinlẹ naa. Eyi ni lati jẹ ki
eto ilera wa ni owo pọọku fun gbogbo eeyan ipinlẹ naa.
Oludasilẹ
ile-ifowopamọ Heritage ọgbẹni Ifie Sekibo sọ pe owo iranwọ yi ma lọ si ẹka eto ọmọ
bib ni gbogbo ile-iwe iwosan ni ipinlẹ Ọyọ. O ni awọn ma sọ yara ilera to n gba
eeyan marundinlaadọta di eyi to n gba eeyan ọgọta. O ni yatọ si atunṣe si
ile-iwosan na, wọn tun ma ohun elo fun awọn ile-iwosan naa ki awọn oṣiṣẹ
ile-iwosan le ṣiṣẹ wọn bi iṣẹ.
Ọgbẹni Sekibo
sọ pe ijọba ipinlẹ Ọyọ jẹ onibara wọn atijọ eyi lo fa ti awọn fi le da si eto
ilera ipinlẹ naa. O ni awọn nigbagbọ ninu eto ilera gomina ipinlẹ Ọyọ atipe o
ma so eso rere fun gbogbo olugbe ipinlẹ naa.
Ninu ayẹyẹ
naa, gomina ipinlẹ Ọyọ, sẹnatọ Abiọla Ajimọbi gbe oriiyin fun ile-ifowopamọ
Heritage fun ifọwọsowọpọ wọn lati jẹ ki eto ilera le gbooro si ipinlẹ naa. O sọ
siwaju si pe iṣẹ awọn kii ṣe lati tun nnkan ṣe nikan amọ lati pese si.
No comments:
Post a Comment