Agbẹnusọ fun
ile-igbimọ aṣofin, ọgbẹni Bukọla Saraki ti jẹ ka mọ pe oun o gbowo ifẹyinti mọ
lọwọ ipinlẹ kwara gẹgẹ bi gomina ipinlẹ naa tẹlẹ.
Ọgbẹni
Saraki sọ eyi fun awọn oniroyin ni ilu Abuja lọjọ iṣẹgun ọsẹ yi. O ni oun ti kọ
lẹta si ipinlẹ kwara ki wọn ye san owo ifẹyinti fun oun mọ gẹgẹ bi gomina tẹlẹ
ni ipinlẹ naa ki o to wọle si ile igbimọ-aṣofin apapọ. O ṣe eyi tori nnkan ti
awọn ajọ kan sọ pe awọn oloṣelu ti wọn ba n gba owo ifẹyinti meji n ja ilu naa
ni ole ni.
O sọ siwaju
pe oun o le kan ni pa fun awọn ẹlẹgbẹ ẹ to n gba iru owo bẹẹ. O gba awọn ipinlẹ
ni imọran pe ki wọn ṣe ofin to ma de gbogbo oloṣelu pe ti o ba ti ni ipo miran
o ni lanfani lati gba owo ifeyinti mọ.
No comments:
Post a Comment