Ile-ifowopamọ
ni orilẹ-ede Naijiria ti ṣeto biliọnu merindinlọgbọn fun awọn to n ṣe agbẹ tabi
ti wọn fẹ bẹrẹ tabi wa owó lati gbe òwò wọn.
Gẹgẹ bi
nnkan ti oludari ile-ifowopamọ Union, ọgbẹni Emeka Emuwa sọ ni ilu Abuja lẹyin
ipade ajọ ile-ifowopamọ ti orilẹ-ede Naijiiria. O ni ajọ naa ti gbe eto naa kalẹ
eyi to maa bẹrẹ lati ọsẹ yi lọ ati e iroyin si ma jade nipa bi a ṣe le jẹ
anfani ẹ.
Awọn
ile-ifowopamọ to wa ninu ajọ naa ni; Oludari Gtbank, Zenith bank, Access bank,
First bank, alabojuto lati CBN ati oludari idagbasoke owo ni CBN. Ninu awọn ajọ
to ma wo iwe awọn to fẹ jẹ anfani owo naa ni; FCMB, Unity bank ati Sterling bank.
Wọn ma yan alaga laarin ara wọn.
Wọn ni awọn
to ba n ṣowo agbẹ abi ṣe kara-kata lo lẹtọ si owo naa. Wọn ni ki onikaluku lọ
si ile-ifowopamọ ẹ lati lọ sọ ohun to nilo lati jẹ ki òwò wọn gboro si.
No comments:
Post a Comment