Ọgbẹni Tẹju Oyelakin ti gbogbo eniyan mọ
si Tẹju Babyface ti jẹ ka mọ pe gbogbo ọdun ti oun fi jẹ apanilẹrin, ifakoko ṣofo
gbaa ni.
O sọ eyi laipẹ yi nigbati o n gba awọn
eeyan nimọran nipa ailowo lọwọ. O ni eeyan ni lati mọ ohun ti Ọlọrun fẹ ko ṣe
nitori igba yẹn gan gan ni eeyan ma ṣe iṣẹ irọrun ti yoo si ni owo lọwọ.
O ni oun ri daju pe awpkọṣe ati olukọ ni
oun fẹ jẹ, eyi ti o n ṣe lọwọ bayi. Nipa eyi ni o fi kọ iwe ‘Secrets of the
Streets’ (Aṣiri ilakaka) eyi ti o n ta lọwọ lọwọ bayi. Iwe naa daleri bi a ṣe
le mu ala wa ṣẹ nipa didi eniyan pataki lawujọ.