Ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin tìpínlẹ̀ Ògùn ti fọwọ́ sí àbá-dòfin tó sọ ‘Moshood
Abiola Polytechic’ di unifásítì. Ó tún ṣe òfin pé kí wọ́n dá pólì míràn sílẹ̀
ni ipokia.
Àbá-dòfin méjì yí jẹ́ àbájáde ìròyìn tí ìgbìmọ̀ ẹ̀kọ́, ìmọ̀ ẹ̀rọ àti sáyẹ́nsì
gbé ka ilé-aṣòfin náà. Alága ìgbìmọ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni Victor Fásànyà ló da lábàá, ọnọrábù Oyènúgà Olúfowóbí àti Olúṣọlá
Bánkọ́lé fọwọ́ si.
Àbá-dòfin yìí mú ìyípadà ba orúkọ ilé-ìwé náà, ó sọ ọ́ di ‘Moshood Abiola
University of Science and Technology’. Ó fàyègbà kí àwọn
ilé-ìwé gíga wà ní agbègbè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
Agbẹnusọ fún ilé-aṣòfin náà, Sùrájù Ìshọ̀lá sọ pé kí wọ́n fi ṣọwọ́ sí gómínà kí ó ba lè buwọ́lùú kó sì dòfin gan gan.

No comments:
Post a Comment