Ní ọjọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀ yí ni ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin tìpínlẹ̀ Bayelsa ṣe ìpàdé tí wọ́n
sì pinu láti yá bílíònù mẹ́ta náírà láti ra ọkọ̀ fún arawọn àti àwọn òṣèlú tó
ń ṣiṣẹ́ fún ìjọba.
Agbẹnusọ ilé-aṣófin náà, ọ̀gbẹ́ni Kombonei Benson ló jẹ́ kí àwọn oníròyìn mọ.
Ó ní ìpàdé nà kò ju ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ, èyí ló fàá tí àwọn ò fi pe àwọn oníròyìn.
Ó ní láti bí ọdún méjì tí àwọn ti jẹ aṣòfin, àwọn kò gbádùn ipò wọn. Ó ní àwọn ọkọ̀
náà wà fún ìrọrùn wọn.
No comments:
Post a Comment