Olórí àwọn ọlọ́pàá ní orílẹ̀-èdè Nàìríjíà, Ibrahim Idris ti sọ pé lọ́dún tó
kọjá nínú bílíọ̀nù mẹ́rìndínlógún náírà tó wà nínú ìsúná-owó fún àwọn ọlọ́pàá,
bílíọ̀nù mẹ́rin péré ni ó tẹ àwọn lọ́wọ́.
Ó sọ èyí nínú ìpàdé tí wọ́n ṣe pẹ̀lú ìgbìmọ̀ ilé-aṣòfin tó ń rí sí ọ̀rọ̀ ọlọ́pàá.
Ibrahim Idris sọ pé owó tí kò tó, tí wọ́n tún ń yọ nínú ẹ̀ yí ni ó fa ìfàsẹ́yìn
fún àwọn ọlọ́pàá láti ṣe iṣẹ́.
Ó sọ síwájú si pé bákan náà ni ọdún 2015, àwọn gba bílíọ̀nù mẹ́jọ ó lé díẹ̀ nínú.
No comments:
Post a Comment