Friday, February 3, 2017

ÌWỌ́DE TÓ FẸ́ WÁYÉ, TÓ Ń FA GBỌ́N’MI-SI-OMI-Ò-TO.




Lọ̀sẹ̀ yí, ògbóńtarìgì akọrin tí a mọ̀ sí 2face fi sórí ẹ̀rọ-ayé-lu-jára pé òun ma ṣe ìwọ́de wọ́rọ́wọ́ láti fi ẹ̀hónú hàn pé ìjọba kò gbìyànjú rárá, nítorí ìwà àìbìkítà sí gbogbo bí nǹkan ṣe rí àtipé wọn ò mú ìlérí wọn ṣẹ èyí tí wọ́n ṣe nígbàtí wọ́n ń ṣe ìpolongo ìdìbò. Ó ní “ó ti to gẹ́lẹ́, gbogbo ìgbà tí nǹkan ǹ ṣẹlẹ̀ ti òun o sọ̀rọ̀ ti dópin.” Ó ṣàlàyé pé pupa ni ẹ̀jẹ̀ gbogbo wa àti pé ka má jẹ́ kí ẹ̀sìn tàbí ohun-kóhun yà wá.

2face tó ti kọrin, tó sì wà nínú àwọn orin kànkan tó bá ìjọba wí nípa ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣè’jọba. Àwọn orin bíi; ‘For instance’, ‘Bush meat’ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Àjọ ẹ̀ ‘Vote not Fight’ tó dásílẹ̀ ní ọdún 2015 láti polongo ìbò tí ò níjà nínú ló fẹ́ lò láti ṣe ìwọ́de náà ní ọjọ́ kẹfà oṣùn yí.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn èèyàn ló ti sọ ẹ̀dùn ọkàn wọn nípa ìwọ́de náà. Lára wọn ni Black Face tí wọ́n jọ wà nínú ẹgbẹ́ akọrin kan náà tẹ́lẹ̀, Ọ̀jọ̀gbọ́n Adétóyè tó jẹ́ olùkọ́ ní ilé-ìwé gíga ti OAU àti gbogbo ọmọ Nàìjíríà.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Adétóyè sọ pé ìwọ́de náà kò tó sí akọrin náà nítorí yàtọ̀ sí ìyàwó tó fẹ́ sílé, ó ní àwọn obìnrin míràn tó bímọ fun. Blackface náà sọ tinú ẹ̀ pé ìwọ́de ò tọ́ sí 2face nítorí kò kàwé, àti pé óní àwọn ohun tí aàrẹ ti ṣe tí akọrin náà ò ṣàkíyèsí. Ó sọ àwọn nǹkan náà bíi; owó-ìrànwọ́ fún àwọn ìpínlẹ̀.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀jọ̀gbọ́n Adétóyè ti tọrọ àforígì, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti bu ẹnu àtọ́ lu ohun tí òun àti Blackface sọ. Ọ̀pọ̀ èèyàn sọ pé irúfẹ́ ọ̀rọ̀ tí ọ̀jọ̀gbọ́n nà sọ kù díẹ̀ káà tó, àwọn kan so pé bí ọjọ́-orí ò ṣe kan t’àgbà náà ní ‘ọ̀jọ̀gbọ́n’ ò kan ọpọlọ. Wọ́n fi Blackface sí ipò àwọn tí wọ́n ń jà fùn àmọ́ wọn ò faramọ́ ìwọ́de náà.

Ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ti jáde làti sọ pé àwọn ò ní jẹ́ kí ìwọ́de náà wáyé nítorí àwọn gbọ́ pé àwọn kan fẹ́ fi àǹfàní nà wu ìwà ìbàjẹ́. Gómínà ìpínlẹ̀ Èkìtì ti sọ pé ọ̀rọ̀ ti àwọn ọlọ́pàá sọ ò dùn uń gbọ́ létí, ó faramọ́ ìwọ́de náà.



Pẹ̀lú awuye-wuye yìí, 2face àti àjọ ẹ̀ ò yí ìpinu wọn padà. Àwọn èèyan púpọ̀ ti ṣèlérí pé àwọn yóò jáde.


No comments:

Post a Comment