Friday, February 3, 2017

ÌJÀ TÓ WÀ LÁÀÁRÍN HARRSONG ÀTI ‘FIVE STAR MUSIC’.




Láti bíi ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ìkùn-sóde ti wà láàárín Harrysong àti ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó orin ẹ̀. Ìdí tí wọ́n fi ń tàbùkù ara wọn ni pé Harrysong kọ̀ láti mú àdéhùn ẹ̀ ṣẹ.

Nínú òkò-ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ síra wọn la ti mọ̀ pé Harrysong bẹ̀bẹ̀ láti wọ ‘Five Star Music’. Wọ́n ní kò mú àdéhùn ṣẹ níbi tó wà tẹ́lẹ̀, wípé gbàmí gbàmí ló ké wá bá àwọn tí àwọn si ràn-án lọ́wọ́ pẹ̀lú iyebíye. Irúfẹ́ ìwà yí ló fẹ́ hùn sí àwọn náà.

Harrysong jẹ́ ka mọ̀ pé irọ́ ni wọ́n pa mọ́ òun àti pé wọ́n yí ìtàn náà. Ó ní ‘Five Star Music’ ló wá bá òun nígbàtí KCEE, ọ̀kan lára olórin wọn pínyà pẹ̀lú ìkejì ẹ̀ PRESH. Ó ní òun ni ó kọ àwọn orin KCEE kànkan. Harrysong ti dá ilé-iṣẹ́ ti ẹ̀ sílẹ̀ ‘Alter Plate’.

Ní ọjọ́bọ̀ nìlù tún yí padà, aṣojú Harrysong sọ pé ọkàn olórin náà fá sí àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀ tó wà ní ‘Fiẹe Star Music’. Ó ní tí àwọn bálè yanjú aáwọ̀ àárín wọn, ‘Alter Plate’ tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó Harrysong lọ́wọ́ ò ní parun.



Harrysong ti tọrọ àforíjì lórí ẹ̀rọ-ayélu-jára. Ó ti yọ gbogbo ohun àbùkù tó sọ àti gbogbo ohun tó ní’ṣe pẹ̀lú ‘Alter Plate’. Daddy Showkey gan la gbọ́ pé ó parí aáwọ̀ náà.

No comments:

Post a Comment