Thursday, February 9, 2017

IṢẸ́ TÍTÚ ÈDÈ GẸ̀Ẹ́SÌ SÍ...




Àyè ti ṣí sílẹ̀ fún ẹni tó nìfẹ́ sí ògbufọ̀ ṣíṣe. 

Ẹ forúkọ sílẹ̀ níbí:  https://t.co/4XuIlzt1qo

Friday, February 3, 2017

LAMPARD TI FẸ̀YÌN TÌ.






Ọmọ agbá-bọ́ọ́lù orílẹ̀-èdè England, tó ti gbá bọ́ọ́lù fún chelsea rí sèpinu lọ́jọ́bọ̀ láti fẹ̀yìntì. Ó tẹ èyí sórí ẹ̀rọ-ayélu-dára ẹ̀. Ó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínláàdọ́ta.

Lampard gbá bọ́ọ́lù fún Chelsea lẹ́ẹ́gbẹ́ta ìgbà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti kúrò níbẹ̀ kó tó fẹ̀yìntì. Ó gbá ayò ọ̀ọ́dúrún s’áwọ̀n, ayò igba ó lé mọ́kànlá ló gbá nígbàtí ó wà ní Chelsea nínú ọ̀ọ́dúrún ayò tó ní.


Ó ní bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣì ń pe òun láti wá gbá bọ́ọ́lù si, òún mọ̀ pé àkókò fún omi tuntun láti rú lèyí. Ó dúpẹ́ fún àǹfàní láti lọ ní ìmọ̀ akọni-mọ̀ọ́gbá.

GÓMÍNỌ̀ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ FỌWỌ́ SÍ ÒFIN Ẹ̀WỌ̀N GBÉRE.





Nílùú Èkó, òfin ti de àwọn ajínigbé. Ẹ̀wọ̀n gbére ni ẹni tí ọwọ́ bá tẹ̀ pé ó jíyángbè, èyí ni òfin tí gómínọ̀ Àḿbọ̀dé fọwọ́ sí. Ó ní tí ẹni tí wọ́n jígbé bá kú, wọ́n ma pa ajínigbé ọ̀ún nà ni.

Ìjìyà wà fún ẹni tó mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe jííyàn gbé, ó wà fún ẹni tó nilé tí wọ́n tọ́jú ẹni tí wọ́n jígbé sí.

‘MOSHOOD ABIOLA POLYTECHNIC’ TI DI UNIFÁSÍTÌ.



 


Ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin tìpínlẹ̀ Ògùn ti fọwọ́ sí àbá-dòfin tó sọ ‘Moshood Abiola Polytechic’ di unifásítì. Ó tún ṣe òfin pé kí wọ́n dá pólì míràn sílẹ̀ ni ipokia.

Àbá-dòfin méjì yí jẹ́ àbájáde ìròyìn tí ìgbìmọ̀ ẹ̀kọ́, ìmọ̀ ẹ̀rọ àti sáyẹ́nsì gbé ka ilé-aṣòfin náà. Alága ìgbìmọ̀ náà, ọ̀gbẹ́ni Victor Fásànyà ló da lábàá, ọnọrábù Oyènúgà Olúfowóbí àti Olúṣọlá Bánkọ́lé fọwọ́ si.

Àbá-dòfin yìí mú ìyípadà ba orúkọ ilé-ìwé náà, ó sọ ọ́ di ‘Moshood Abiola University of Science and Technology’. Ó fàyègbà kí àwọn ilé-ìwé gíga wà ní agbègbè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.
 
Agbẹnusọ fún ilé-aṣòfin náà, Sùrájù Ìshọ̀lá sọ pé kí wọ́n fi ṣọwọ́ sí gómínà kí ó ba lè buwọ́lùú kó sì dòfin gan gan.

ILÉ-ÌGBÌMỌ̀ AṢÒFIN NÍ ÌPÍNLẸ̀ BAYELSA MA YÁ’WÓ RỌKỌ̀.






Ní ọjọ́bọ̀ ọ̀sẹ̀ yí ni ilé-ìgbìmọ̀ aṣòfin tìpínlẹ̀ Bayelsa ṣe ìpàdé tí wọ́n sì pinu láti yá bílíònù mẹ́ta náírà láti ra ọkọ̀ fún arawọn àti àwọn òṣèlú tó ń ṣiṣẹ́ fún ìjọba.

Agbẹnusọ ilé-aṣófin náà, ọ̀gbẹ́ni Kombonei Benson ló jẹ́ kí àwọn oníròyìn mọ. Ó ní ìpàdé nà kò ju ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ, èyí ló fàá tí àwọn ò fi pe àwọn oníròyìn. Ó ní láti bí ọdún méjì tí àwọn ti jẹ aṣòfin, àwọn kò gbádùn ipò wọn. Ó ní àwọn ọkọ̀ náà wà fún ìrọrùn wọn.

ÌJÀ TÓ WÀ LÁÀÁRÍN HARRSONG ÀTI ‘FIVE STAR MUSIC’.




Láti bíi ọ̀sẹ̀ tó kọjá ni ìkùn-sóde ti wà láàárín Harrysong àti ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó orin ẹ̀. Ìdí tí wọ́n fi ń tàbùkù ara wọn ni pé Harrysong kọ̀ láti mú àdéhùn ẹ̀ ṣẹ.

Nínú òkò-ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ síra wọn la ti mọ̀ pé Harrysong bẹ̀bẹ̀ láti wọ ‘Five Star Music’. Wọ́n ní kò mú àdéhùn ṣẹ níbi tó wà tẹ́lẹ̀, wípé gbàmí gbàmí ló ké wá bá àwọn tí àwọn si ràn-án lọ́wọ́ pẹ̀lú iyebíye. Irúfẹ́ ìwà yí ló fẹ́ hùn sí àwọn náà.

Harrysong jẹ́ ka mọ̀ pé irọ́ ni wọ́n pa mọ́ òun àti pé wọ́n yí ìtàn náà. Ó ní ‘Five Star Music’ ló wá bá òun nígbàtí KCEE, ọ̀kan lára olórin wọn pínyà pẹ̀lú ìkejì ẹ̀ PRESH. Ó ní òun ni ó kọ àwọn orin KCEE kànkan. Harrysong ti dá ilé-iṣẹ́ ti ẹ̀ sílẹ̀ ‘Alter Plate’.

Ní ọjọ́bọ̀ nìlù tún yí padà, aṣojú Harrysong sọ pé ọkàn olórin náà fá sí àwọn ẹgbẹ́ ẹ̀ tó wà ní ‘Fiẹe Star Music’. Ó ní tí àwọn bálè yanjú aáwọ̀ àárín wọn, ‘Alter Plate’ tó jẹ́ ilé-iṣẹ́ tó ń mójútó Harrysong lọ́wọ́ ò ní parun.



Harrysong ti tọrọ àforíjì lórí ẹ̀rọ-ayélu-jára. Ó ti yọ gbogbo ohun àbùkù tó sọ àti gbogbo ohun tó ní’ṣe pẹ̀lú ‘Alter Plate’. Daddy Showkey gan la gbọ́ pé ó parí aáwọ̀ náà.