Agbabọọlu fun ikọ
Liverpool ati ikọ Egypt naa ni o gba ami idalọla agbabọọlu t’o dara julọ ni
Africa ti BBC fun Ọdun 2017. Agbabọọlu naa da awọn akẹgbẹ rẹ bii Sadio Mane,
Piere Emerick Aubameyang, Naby Keita ati Victor Moses lati gba ami idalọla naa.
Salah ti gba bọọlu
kandinlogun sawọn ninu gbogbo idije ni saa igbabọọlu yii fun ikọ Liverpool lati
igba ti wọn ti ra kuro ni ikọ Roma. Agbabọọlu naa sọ wi pe; “Inu oun dun, ayọ
oun kun, oun si ka ara oun kun ẹni ti Ọlọrun fẹran julọ ti o fi awọn agbabọọlu
aramanda kẹ, nitori bi ko bas i ti wọn, ko si oun”.
Ni bayii, Sallah ni
agbabọọlu t’o gba bọọlu sawọn julọ ni Agbakuta liigi gẹẹsi, pẹlu bọọlu mẹtala,
bakan naa, ni o gba bọọlu marun-un s’awọn, o si tun ṣe irawo meji ti awọn
oloyinbo n pe ni assist lati gbe ikọ Egypt pegede fun idije bọọlu agbaye fun
igba akọkọ lati Ọdun 1990.
No comments:
Post a Comment