Monday, December 11, 2017

GOOGLE L’ÉDÈ YORÙBÁ.




Kìí ṣe ìròyìn tuntun pé Google ló kù tá ǹ gbọ́ọ́ lóríi rédíò àti tẹlẹfíṣán. Ohun tó ṣeni láàánú ni pé bí wọ́n ṣe polówó ẹ̀ tó, kò sí ìpolówó ní èdè abínibí yálà Igbo, Hausa tàbí Yorùbá.

Ohun tó ṣeni ní kàyéfì ni pé Google ní àwọn èdè yí tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa. Ìbéèrè ibẹ̀ ni pé ‘kí ló dé tí wọn ò ṣe ìpolówó náà ní èdè Yorùbá tàbí sọ bí a ṣe lè lo Google l’édè Yorùbá?’

Ẹ jẹ́ kí a wo bí a ṣe lè fi èdè Yorùbá wa nǹkan lóri Google:


1.     Ta bá tẹ google.com.ng sórí ìkànì wa, ó ma ṣí sí irú àwòrán ìsàlẹ̀ yí



2.     Ẹ jẹ́ ka mú èdè Yorùbá, ẹ sakiyesi pe ko si ede yoruba laarin awọn ede abẹ yi nitori ohun ni a mu


3.     Ta ba wa tẹ 'asa yoruba' gẹgẹ bi ohun ti an wa, ede yorub lo ma gbe gbogbo abajade naa wa.
.

Ó da ka ma gbé àṣà wa ga nítorí Yoòbá bọ̀ wọ́n ní ‘ Ohun t’ónígbá bá pe igbá ẹ̀ ni wọ́n ma ba pè é.’ atipe nání nànì nání, ohun aní là ń nání.

No comments:

Post a Comment