Ajọ LASIEC
ti fun ọgbẹni Aderibigbe Imọlẹ Oluwafẹmi ati Ọlamoyegun Simeon Ṣẹgun ti ẹgbẹ
Accord ni iwe ẹri lati di kansẹlọ Ward F ati Ward H ti odi-Olowo/Ojuwoye.
Alaga ajọ to
ri si idajọ idibo ijọba ibilẹ, Adajọ Ayọtunde Philips, ẹni ti ọgbẹni Olumide
Lawal ṣoju ẹ gboriyin fun ẹgbẹ Accord. O ni eyi jẹ ileri ti awọn ṣe ninu ipade
alẹnu-lọrọ ki wọn to dibo lati ri peidajọ ododo waye ti ẹgbẹ kankan ba ṣakiyesi
mọdaru ninu ibo naa.
Alaga igbimọ
naa rọ awọn kansẹlọ meji naa ki wọn fi ọwọ sowọpọ pẹlu awọn alaga wọn. Wọn jẹ
ka mọ pe ẹjọmẹtadinlọgbọn lawọn gba lati ọwọ ẹgbẹ nipa idibooṣun keje, awọn
meji yi nikan lo jawe olubori.
No comments:
Post a Comment