Wednesday, December 20, 2017
Wednesday, December 13, 2017
Tuesday, December 12, 2017
MOHAMMED SALAH GBA AMI-Ẹ̀YẸ AGBÁBỌ́Ọ̀LÙ T’Ó DÁŃGÁJÍÁ JÙLỌ NÍ ILẸ̀-AFRICA.
Agbabọọlu fun ikọ
Liverpool ati ikọ Egypt naa ni o gba ami idalọla agbabọọlu t’o dara julọ ni
Africa ti BBC fun Ọdun 2017. Agbabọọlu naa da awọn akẹgbẹ rẹ bii Sadio Mane,
Piere Emerick Aubameyang, Naby Keita ati Victor Moses lati gba ami idalọla naa.
Salah ti gba bọọlu
kandinlogun sawọn ninu gbogbo idije ni saa igbabọọlu yii fun ikọ Liverpool lati
igba ti wọn ti ra kuro ni ikọ Roma. Agbabọọlu naa sọ wi pe; “Inu oun dun, ayọ
oun kun, oun si ka ara oun kun ẹni ti Ọlọrun fẹran julọ ti o fi awọn agbabọọlu
aramanda kẹ, nitori bi ko bas i ti wọn, ko si oun”.
Ni bayii, Sallah ni
agbabọọlu t’o gba bọọlu sawọn julọ ni Agbakuta liigi gẹẹsi, pẹlu bọọlu mẹtala,
bakan naa, ni o gba bọọlu marun-un s’awọn, o si tun ṣe irawo meji ti awọn
oloyinbo n pe ni assist lati gbe ikọ Egypt pegede fun idije bọọlu agbaye fun
igba akọkọ lati Ọdun 1990.
Monday, December 11, 2017
GOOGLE L’ÉDÈ YORÙBÁ.
Kìí ṣe ìròyìn tuntun pé Google ló kù tá ǹ gbọ́ọ́ lóríi rédíò àti tẹlẹfíṣán.
Ohun tó ṣeni láàánú ni pé bí wọ́n ṣe polówó ẹ̀ tó, kò sí ìpolówó ní èdè abínibí
yálà Igbo, Hausa tàbí Yorùbá.
Ohun tó ṣeni ní kàyéfì ni pé Google ní àwọn èdè yí tó ń ṣiṣẹ́ dáadáa.
Ìbéèrè ibẹ̀ ni pé ‘kí ló dé tí wọn ò ṣe ìpolówó náà ní èdè Yorùbá tàbí sọ bí a ṣe
lè lo Google l’édè Yorùbá?’
Ẹ jẹ́ kí a wo bí a ṣe lè fi èdè Yorùbá wa nǹkan lóri Google:
1.
Ta
bá tẹ google.com.ng sórí ìkànì wa, ó ma ṣí sí irú àwòrán ìsàlẹ̀ yí
2. Ẹ jẹ́ ka mú èdè Yorùbá, ẹ sakiyesi pe ko si ede yoruba laarin awọn ede abẹ yi nitori ohun ni a mu
Ó da ka ma gbé àṣà wa ga nítorí Yoòbá bọ̀ wọ́n ní ‘ Ohun t’ónígbá bá pe
igbá ẹ̀ ni wọ́n ma ba pè é.’ atipe nání nànì nání, ohun aní là ń nání.
LASIEC FUN KANSẸLỌ LATI ẸGBẸ ACCORD NI IWE ẸRI.
Ajọ LASIEC
ti fun ọgbẹni Aderibigbe Imọlẹ Oluwafẹmi ati Ọlamoyegun Simeon Ṣẹgun ti ẹgbẹ
Accord ni iwe ẹri lati di kansẹlọ Ward F ati Ward H ti odi-Olowo/Ojuwoye.
Alaga ajọ to
ri si idajọ idibo ijọba ibilẹ, Adajọ Ayọtunde Philips, ẹni ti ọgbẹni Olumide
Lawal ṣoju ẹ gboriyin fun ẹgbẹ Accord. O ni eyi jẹ ileri ti awọn ṣe ninu ipade
alẹnu-lọrọ ki wọn to dibo lati ri peidajọ ododo waye ti ẹgbẹ kankan ba ṣakiyesi
mọdaru ninu ibo naa.
Alaga igbimọ
naa rọ awọn kansẹlọ meji naa ki wọn fi ọwọ sowọpọ pẹlu awọn alaga wọn. Wọn jẹ
ka mọ pe ẹjọmẹtadinlọgbọn lawọn gba lati ọwọ ẹgbẹ nipa idibooṣun keje, awọn
meji yi nikan lo jawe olubori.
HARRYSONG SỌ KUBU ỌRỌ SI GOMINA IPINLẸ DELTA.
Harrysong tii ṣe akọrin ọmọ orilẹ-ede Naijiria ti sọrọ
lori rogbodiyan to n ṣẹlẹ laaarin abule meji ni ipinlẹ Delta. Adugbo Aldja ati
Igbe Ijaw ti n ba arawọn ja ọjọ ti pẹ amọ ijọba to wa lori aleefa ko fi oju ibẹ
woran rara.
Aanu ṣe
Harrysong tori Gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa n ṣowo ni ipinlẹ naa eyi to yẹ
ko ma daabo bo awọn ara ipinlẹ naa to
dibo yan si ip. Ija aarinn Urhobo ati Ijaw ni ipinlẹ naa ti pẹ, o si ti sọ ọpọ
eniyan di ainile lori.
Ninu nnkaan
ti Harrysong fi ṣọwọ si INSTAGRAM ati TWITTER ẹ loni ni pe awọn to n gbe ni
agbegbe mejeeji naa nilo adura.
SKIIBII KURO NI “FIVE STAR MUSIC”.
Loni ni KCEE
to jẹ ọkan lara awọn akọrin to wa ni “ Five
Star Music” kẹdun pe Skiibii ti kuro lọdọ wọn. Ẹdun ọkan ẹ lo fi kọ
eyi sori INSTAGRAM ẹ pe:
“ Arakunrin,
ọrẹ mi... Irin ajo to dara ni lati wa ninu ‘ Fiẹe Star Music’ ni gbogbo ọdun
yi. Bo ṣe n lọ da duro gẹgẹ bi ọkunrin, mo gbero ohun rere si ẹ ati pe gbogbo
wa wa lẹyin ẹ bi ike lati ti ẹ lẹyin”
A ri pe
Skiibii ti ni ọwọ ti ẹ to pe ni ; “More Grace Music World”. Ajọsepọ to peye wa
laarin Skiibii ati awọn to wa ni “Five Star
Music” nitori o ṣi ni ayẹyẹ kan pẹlu wọn ni oọun to n bọ.
Subscribe to:
Posts (Atom)