Wednesday, July 26, 2017

ÌLÚ ÌṢÀWÒ LẸ́YÌN TÍ ÀWỌN ELÉPO-RỌ̀BÌ LỌ TÁN.






Ni bii ọdun meji ṣeyin, ọkan awọn olugbe Iṣawo ni Ikorodu wa loke. Ibẹru-bojo ni olukuluku fi n gbe. Pupọ ninu awọn kankan to kọle si adugbo yi ti ko laya kẹbọ-jẹ gan-an fẹsẹfẹ. Ko si ohun to n le wọn ju awọn elepo rọbi. Wọn ṣe’jọba bi ko sẹni to ma mu wa.

Iṣẹ epo rọbi o dede gbilẹ ni agbegbe Iṣawo, aipẹka iroko wọn ni wọn fi di igi nla. Awọn Ijaw ni o lọ n wa epo naa eyi to gba agbegbe naa kọja. Ọpọ igba ni ibi ti wọn ti n wa epo yi ma n bu-gba ti ọpọ ninu awọn to lọ maa n ku amọ wọn ko fi iṣẹ naa silẹ. Ti wọn ba ti fi ọjọ mẹta daro awọn to ku, wọn tu ma pada si idi ẹ.

Iwadii fi han pe igi ni awọn ẹya Ijaw yi maa n ṣẹ ta tẹlẹ ti awọn miran ninu wọn si n pẹja ta. Amọ ṣa dede ni iṣẹ epo-rọbi naa gbilẹ ti awọn ọdọmọkunrin adugbo naa gba iṣẹ ‘carrier’ (awọn to n bawọn ru epo naa jade) ti awọn obinrin si di agbesun.
Iṣẹ epo-rọbi ti n lọ si bi ọdun mẹta si mẹrin ki wahala wọn to bẹrẹ. Nigba ti iṣẹ na n lọ loju-mejeeji, ọpọ to n gbe ni adugbo na ni kii ra epo ni ile-epo. Ọja n ya ladugbo, gbogbo nkan si n lọ deede. Amọ ni akoko igba ti wọn o ba riṣẹ ṣe, nnkan o ni rọgbọ lagbegbe. Bi awọn Ijaw yi ṣe n gbe ẹdiyẹ ni wọn ma gbe ẹran, ti aguntan naa a ma di awati. Nigba ti wṣn ṣe edori pe wọn gbe eyan wọn gba owo ni o ṣẹ ka Ijọba lara.Eyi ti wọn gbe to tu wọn fo ni Alufa Redeem ti wọn jigbe ni ọdun 2015. Eyi lo jẹ ki awọn ọmọ ogun gba agugbo naa kan.
Awọn ologun jagun jagun bori wọn. O n lọ si bii ọdun meji ti awọn elepo rọbi ti lọ amọ nkan o ti pada si ipo. Oju apa ko jọ oju ara mọ, bo tilẹ jẹ pe awọn ara-adugbo n sun daada nitori awọn ologun ṣi wa nibẹ karakata o tii pada si ipo. Gbogbo awọn to ni ṣọbu si oju ọna ti n tii pa, ọpọ to kolọ ni ko pada wa mọ. Pa ban-bari ẹ ni pe ọpọ ni ko fẹ gbale si adugbo naa nitori iṣẹlẹ to ti kọja. Ohun ti ko lọ deede yi tun n jẹ ki awọn eeyan ma ko lọ si ibomiran. Ohun to dun awọn olugbe Iṣawo ni pe igbo ti ijọba je ti n wu pada, ko ma dipe o ma wu tan awọn araabi ma pada wa.
Iroyin ọna tuntun ti ijọba Eko fẹ ṣe lo tun n mu ireti  diẹ diẹ wa, igbagbọ awọn eeyan ni pe ti wọn ba ṣe ọna naa tan yoo mu idagbasoke ba agbegbe naa ati pe awọn eeyan o ni maa fi oju iṣẹlẹ to ti ṣẹ nibẹ wo ibẹ mọọ.

No comments:

Post a Comment