Wednesday, July 26, 2017

ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ-ÌWÉ GÍGA TI ÌJỌBA NÍ ỌYẸ́ ÈKÌTÌ FI ÌHÓNÚ HÀN.






Iroyin ti a gbọ ni pe awọn akẹkọọ ile-iwe giga ti ijọba, Ọyẹ Ekiti fihonu han lanọọ niwaju ile-ẹkọ wọn. Wọn n fihonu han nitori bi awọn oludari ile-ẹkọ na ṣe n ṣakoso ile-eiwe naa.
Ẹsun ti wọn ka si ẹsẹ awọn oludari ile-ẹkọ naa ni;
1.      Wọn ko fun awọn ọmọ ile-iwe kan kan ni nọmba idanimọ, eyi ti wọn ti wa ni saa keji ọdun kinni.
2.      Ohun miran ti wọn sọ ni pe awọn o faramọ bi wọn ṣe yọ oludari eto ọmọ ile-iwe, Ọmọwe Adeyẹmi ẹni to faramọ eto oṣelu laarin awọn ọmọ ile-iwe. Ọmọwe Adeyẹmi naa ni wọn yọ lai si ẹsun kan kan ka si lẹsẹ o di ọdun 2018 ki saa ẹ to tan.
3.      Wọn ni awọn o nifẹ si ẹni ti wọn yan ki o rọpọ ẹ iyẹn Ọmọwe Malọmọ ti gbogbo wọn mọ si ‘Maloo’.
Iwọde wọn bẹrẹ ni ago meje aarọ ti wọn si gbe igi di abawọle ile-iwe na. Akitiyan awọn eeyan to leekan lọwọ ninu ile-iwe naa lati ba awọn ọmọ ile-iwe naa sọrọ jasi pabo nitori wọn ko gba ẹnikẹni laye lati sọrọ. Koda wọn ju oko ati ọra-omi lu Ọmọwe Faṣina nitori wọn ro boya o wa lara awọn to gbero lati yọ Ọmọwe Adeyemi nipo.

No comments:

Post a Comment