Sunday, July 23, 2017

FÚN ÌMỌ́ TÓ-TÓ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ.






Ijọba ipinlẹ Eko ti gbe eto kan kalẹ to ma ri si itoju ati dida idọti nu ni ipinlẹ naa. Eto yi ni wọn pe ni “Cleaner Lagos” to tumọ si ‘Imọ to to Eko’. Eto yi ma pese iṣẹ fun awon eeyan bi ọgọrun marun-un. Igbani wọle ti kọja fun awọn to ma bawọn ṣiṣẹ wọn si ti ṣe ayẹwo ilera ara fun awọn ti wọn mu.

Lori eto kan ninu redio, alabojuto ‘imọ to-to Eko’ jẹ ka mọ pe eyi yatọ si eto LAWMA tijọsi. O ni awọn to ma mojuto agbegbe kankan ma jẹ ẹni to wa lati agbegbe naa, eyi si ni bi wọn ṣe ṣe igbani wọle fun eto naa. Wọn beere nipa awọn ọkọ to maa n ko idọti ati ibi ti wọn yoo maa da idọti naa si, o dahun pe awọn iyẹn a ṣoro. O ni awọn to n ko idọti tẹlẹ gbe ijọba ipinlẹ Eko lọ ile-ẹjọ nitori wọn ro pe ijọba o mu adehun wọn ṣẹ amọ wọn padanu bọ nibẹ nitori o ti pẹ ti adehun wọn ti pari. Awọn ile-iṣẹ yi ati tuntun miran lo maa ma ko idọti ti wọn ba bẹrẹ ati pe ijọba ipinlẹ Eko ti tọka si aye tuntun ti wọn yoo ma da ilẹ naa si.

Awọn ipolongo nipa ilanilọyẹ ti n lọ lori ẹrọ alatagba nipa eto naa. A gbọ pe oṣun kẹjọ gan gan ni eto yi ma bẹrẹ tori ninu oṣun kan-na yi ni awọn ti wọn ṣe ayẹwo-ilera ara ma gba lẹta ipeni-siṣẹ.

No comments:

Post a Comment