Opopona Ketu
si Ikorodu wa lara awọn ọna ni ipinlẹ Eko ti ọkọ maa n gba julọ. Eyi le wa lara
awọn idi to fi jẹ pe ọna yi ni wọn ti kọkọ bẹrẹ BRT. Ọna yi ni wọn pinsi meji,
apa kan fun awọn to n lọ, ekeji fun awọn to n bọ. Leeni mẹta lo wa ni apa
kankan, leeni kan fun BRT ti meji toku si jẹ ti awon awakọ aladani ati elero.
Ki ọna naa
to gboro bayi, awọn to n ti Ikorodu lọ si Ketu a maa lo to wakati meji si mẹta
loju’na yi. Amọ nigbati ijọba ipinlẹ Eko ti da ọda si, sunkẹrẹ-fakẹrẹ ti dinku.
Ijọba ipinle Eko n sa ipa wọn lati dẹkun sunkẹrẹ-fakẹrẹ oju popona yi amọ o
dabi ọni pe o kan dinku ni.
Bo tilẹ jẹ
pe loju o dabi ẹni pe a ko le dẹkun sunkẹrẹ-fakẹrẹ loju’na yi amọ didẹkun ẹ wa
lọwọ ijọba ati awọn awakọ oju popona naa.gbogbo wa gẹgẹ bi ijọba la ni ipa la
ti ko. Awọn ohun ti a le ṣe lati dẹkun sunkẹrẹ-fakẹrẹ lopopona yi ni;
-
Gbogbo ofin oju
popona ni ki ijọba ri pe awọn awakọ n tẹle. Eyi ni lati ri pe awọn to n ri si
igboke-gbodo ọkọ wa ni ibi to yẹ ki wọn wa lasiko to yẹ.
-
Ki ijọba ṣe atunṣe
si ọna naa ni iwaju ọja mile 12 gan gan. Awọn koto kan wa niwaju ọja mile 12
eyi to maa n fa ki awakọ rọra kọja nibẹ ti o si maa n jẹ ki wọn ba ara wọn nibẹ
to si ma di sunkẹrẹ-fakẹrẹ.
-
Ki ijọba paṣẹ fun
awọn ajọ to risi kiko koto-adominu nitori igba ojo, awon koto-adominu naa maa n
kun o si ma fa ki omi ya si oju popona naa. Omi to n ya si ona yi naa lo n fa
koto popona naa.
-
Fifi ofin mu awọn
eeyan ṣe koko ti a ba fẹ dẹkun sunkẹrẹ-fakẹrẹ oju ona Ikorodu si Ketu yii.Awọn
to yẹ ki awọn ajọ ijọba to n ri si opopona naa ma mu ni awọn to n taja lẹbaa ọna
naa.
-
Suuru awọn awakọ ṣe
koko loju’na yi nitori ọpọ igba ni sunkẹrẹ-fakẹrẹ ma n waye nitori ọkọ kan kolu
ekeji.
-
Yatọ si suuru, awakọ
gbọdọ mọ ipo ti ọkọ ti oun gbe si ọna wa ki o ma baa taku si ona.
Mo mọ pe ijọba
ipinlẹ Eko n gbiyanju lati ri pe igboke-gbodo ọkọ n lọ gere amọ ohun pupọ ni wọn
ni lati fọkan si kii ṣe pipese ọkọ nikan ni ki wọn tẹpẹlẹ mọ. Eyi to ju wa lọwọ
awọn ara ilu nitori awa gan la n rin popona yi ju. O tumọ si pe ki a ma da idọti
wa sinu koto-idominu, ti a ba si ri irufẹ eeyan to n ṣebẹ o yẹ ki a tọka si. Ti
ijọba, awakọ ati awọn ara-ilu to n gbe ni agbegbe ibi ti ona naa wa bale tẹle
ilana yi, o da mi loju pe sunkẹrẹ-fakẹrẹ ma di ohun igbagbe lọna naa.
No comments:
Post a Comment