Friday, July 28, 2017

NÀÍJÍÍRÍÀ PÀDÁNÙ TÓ MÍLÍỌ̀NÚ MÁRÙNDÍNLÓGÚN SỌ́WỌ́....





Ile aṣoju-ṣofin ti jẹ ka mọ pe orilẹ-ede Naijiiria n padanu to miliọnu marundinlogun sọwọ awọn to n ta nnkan ini orilẹ-ede naa ni ọna aitọ. Awọn nkan ini naa ni wọn ta ku nigbati wọn n sọ ile-iṣẹ to n pese ina di ti aladani, awọn nnkan wonyi ni ko si fun pipese ina. Wọn gbọ pe awọn kan n ta, awọn miran si n ji awọn ohun ini yi ni wọn wa ni ki igbimọ to n ri si rira ati tita ohun ini ijọba ṣewadii nipa ọrọ naa.
Ninu abọ igbimọ ti wọn ṣe ni anọ ni wọn ti sọpe ijọba Naijiria tọju ohun ini wọn yi si akata NELMCO, eyi ti wọn ni ko ta ohun ini naa lati ri owo san gbese ti ile-iṣẹ naa jẹ ki wọn to taa. Eyi ti o nira lati ṣe. Wọn ni iwadii wọn fi han pe ọpọ ninu awọn ini yi ni wọn ta ni owo ti o kaju ilu, omiran ni wọn fun ileeṣẹ to n pese ina. Igbimọ naa jẹ ko di mimọ pe ṣiṣe ohun ini bayi ti pẹ lati aye Niger dam, ECN ati NEPA.
Wọn jẹ ko ye awọn oniroyin pe awọn ajọ to n risi titọju ohun ini orilẹ-ede Naijiiria n fa ẹru naa mọrawọn lọwọ amọ bayi o ti jasi ọwọ NELMCO wọn si n duro lati gba aṣẹ lọwọ NCP ki wọn to bẹrẹ si ni ta awọn ẹru naa. Ipade lori abọ ohun ini naa ma tẹsiwaju leni lati gbọ ọrọ lẹnu gbogbo ajọ ti ọrọ kan.

Wednesday, July 26, 2017

ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ-ÌWÉ GÍGA TI ÌJỌBA NÍ ỌYẸ́ ÈKÌTÌ FI ÌHÓNÚ HÀN.






Iroyin ti a gbọ ni pe awọn akẹkọọ ile-iwe giga ti ijọba, Ọyẹ Ekiti fihonu han lanọọ niwaju ile-ẹkọ wọn. Wọn n fihonu han nitori bi awọn oludari ile-ẹkọ na ṣe n ṣakoso ile-eiwe naa.
Ẹsun ti wọn ka si ẹsẹ awọn oludari ile-ẹkọ naa ni;
1.      Wọn ko fun awọn ọmọ ile-iwe kan kan ni nọmba idanimọ, eyi ti wọn ti wa ni saa keji ọdun kinni.
2.      Ohun miran ti wọn sọ ni pe awọn o faramọ bi wọn ṣe yọ oludari eto ọmọ ile-iwe, Ọmọwe Adeyẹmi ẹni to faramọ eto oṣelu laarin awọn ọmọ ile-iwe. Ọmọwe Adeyẹmi naa ni wọn yọ lai si ẹsun kan kan ka si lẹsẹ o di ọdun 2018 ki saa ẹ to tan.
3.      Wọn ni awọn o nifẹ si ẹni ti wọn yan ki o rọpọ ẹ iyẹn Ọmọwe Malọmọ ti gbogbo wọn mọ si ‘Maloo’.
Iwọde wọn bẹrẹ ni ago meje aarọ ti wọn si gbe igi di abawọle ile-iwe na. Akitiyan awọn eeyan to leekan lọwọ ninu ile-iwe naa lati ba awọn ọmọ ile-iwe naa sọrọ jasi pabo nitori wọn ko gba ẹnikẹni laye lati sọrọ. Koda wọn ju oko ati ọra-omi lu Ọmọwe Faṣina nitori wọn ro boya o wa lara awọn to gbero lati yọ Ọmọwe Adeyemi nipo.

ÌLÚ ÌṢÀWÒ LẸ́YÌN TÍ ÀWỌN ELÉPO-RỌ̀BÌ LỌ TÁN.






Ni bii ọdun meji ṣeyin, ọkan awọn olugbe Iṣawo ni Ikorodu wa loke. Ibẹru-bojo ni olukuluku fi n gbe. Pupọ ninu awọn kankan to kọle si adugbo yi ti ko laya kẹbọ-jẹ gan-an fẹsẹfẹ. Ko si ohun to n le wọn ju awọn elepo rọbi. Wọn ṣe’jọba bi ko sẹni to ma mu wa.

Iṣẹ epo rọbi o dede gbilẹ ni agbegbe Iṣawo, aipẹka iroko wọn ni wọn fi di igi nla. Awọn Ijaw ni o lọ n wa epo naa eyi to gba agbegbe naa kọja. Ọpọ igba ni ibi ti wọn ti n wa epo yi ma n bu-gba ti ọpọ ninu awọn to lọ maa n ku amọ wọn ko fi iṣẹ naa silẹ. Ti wọn ba ti fi ọjọ mẹta daro awọn to ku, wọn tu ma pada si idi ẹ.

Iwadii fi han pe igi ni awọn ẹya Ijaw yi maa n ṣẹ ta tẹlẹ ti awọn miran ninu wọn si n pẹja ta. Amọ ṣa dede ni iṣẹ epo-rọbi naa gbilẹ ti awọn ọdọmọkunrin adugbo naa gba iṣẹ ‘carrier’ (awọn to n bawọn ru epo naa jade) ti awọn obinrin si di agbesun.
Iṣẹ epo-rọbi ti n lọ si bi ọdun mẹta si mẹrin ki wahala wọn to bẹrẹ. Nigba ti iṣẹ na n lọ loju-mejeeji, ọpọ to n gbe ni adugbo na ni kii ra epo ni ile-epo. Ọja n ya ladugbo, gbogbo nkan si n lọ deede. Amọ ni akoko igba ti wọn o ba riṣẹ ṣe, nnkan o ni rọgbọ lagbegbe. Bi awọn Ijaw yi ṣe n gbe ẹdiyẹ ni wọn ma gbe ẹran, ti aguntan naa a ma di awati. Nigba ti wṣn ṣe edori pe wọn gbe eyan wọn gba owo ni o ṣẹ ka Ijọba lara.Eyi ti wọn gbe to tu wọn fo ni Alufa Redeem ti wọn jigbe ni ọdun 2015. Eyi lo jẹ ki awọn ọmọ ogun gba agugbo naa kan.
Awọn ologun jagun jagun bori wọn. O n lọ si bii ọdun meji ti awọn elepo rọbi ti lọ amọ nkan o ti pada si ipo. Oju apa ko jọ oju ara mọ, bo tilẹ jẹ pe awọn ara-adugbo n sun daada nitori awọn ologun ṣi wa nibẹ karakata o tii pada si ipo. Gbogbo awọn to ni ṣọbu si oju ọna ti n tii pa, ọpọ to kolọ ni ko pada wa mọ. Pa ban-bari ẹ ni pe ọpọ ni ko fẹ gbale si adugbo naa nitori iṣẹlẹ to ti kọja. Ohun ti ko lọ deede yi tun n jẹ ki awọn eeyan ma ko lọ si ibomiran. Ohun to dun awọn olugbe Iṣawo ni pe igbo ti ijọba je ti n wu pada, ko ma dipe o ma wu tan awọn araabi ma pada wa.
Iroyin ọna tuntun ti ijọba Eko fẹ ṣe lo tun n mu ireti  diẹ diẹ wa, igbagbọ awọn eeyan ni pe ti wọn ba ṣe ọna naa tan yoo mu idagbasoke ba agbegbe naa ati pe awọn eeyan o ni maa fi oju iṣẹlẹ to ti ṣẹ nibẹ wo ibẹ mọọ.

Sunday, July 23, 2017

FÚN ÌMỌ́ TÓ-TÓ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ.






Ijọba ipinlẹ Eko ti gbe eto kan kalẹ to ma ri si itoju ati dida idọti nu ni ipinlẹ naa. Eto yi ni wọn pe ni “Cleaner Lagos” to tumọ si ‘Imọ to to Eko’. Eto yi ma pese iṣẹ fun awon eeyan bi ọgọrun marun-un. Igbani wọle ti kọja fun awọn to ma bawọn ṣiṣẹ wọn si ti ṣe ayẹwo ilera ara fun awọn ti wọn mu.

Lori eto kan ninu redio, alabojuto ‘imọ to-to Eko’ jẹ ka mọ pe eyi yatọ si eto LAWMA tijọsi. O ni awọn to ma mojuto agbegbe kankan ma jẹ ẹni to wa lati agbegbe naa, eyi si ni bi wọn ṣe ṣe igbani wọle fun eto naa. Wọn beere nipa awọn ọkọ to maa n ko idọti ati ibi ti wọn yoo maa da idọti naa si, o dahun pe awọn iyẹn a ṣoro. O ni awọn to n ko idọti tẹlẹ gbe ijọba ipinlẹ Eko lọ ile-ẹjọ nitori wọn ro pe ijọba o mu adehun wọn ṣẹ amọ wọn padanu bọ nibẹ nitori o ti pẹ ti adehun wọn ti pari. Awọn ile-iṣẹ yi ati tuntun miran lo maa ma ko idọti ti wọn ba bẹrẹ ati pe ijọba ipinlẹ Eko ti tọka si aye tuntun ti wọn yoo ma da ilẹ naa si.

Awọn ipolongo nipa ilanilọyẹ ti n lọ lori ẹrọ alatagba nipa eto naa. A gbọ pe oṣun kẹjọ gan gan ni eto yi ma bẹrẹ tori ninu oṣun kan-na yi ni awọn ti wọn ṣe ayẹwo-ilera ara ma gba lẹta ipeni-siṣẹ.