Thursday, March 22, 2018

Lewandowski: Super Eagles yoo la ọna lati koju Senegal



Gbajugbaja agbabọọlu orilẹ-ede Poland, Robert Lewandoski, ti sọrọ lori ohun to faa ti orilẹ-ede Poland fi yan ikọ Super Eagles gẹgẹ bii ọkan lara awọn ikọ ti yoo ba dije ọlọrẹsọrẹ fun igbaradi idije ife ẹyẹ agbaye ti yoo waye lorilẹ-ede Russia losu kẹfa ọdun 2018.
Ninu ọrọ kan to sọ lori ikanni ayelujara ajọ to n samojuto ere bọọlu lorilẹede Poland, Lewandoski salaye wi pe, nitori awọn ti ikọ agbabọọlu Poland yoo koju ninu ipele akọkọ nibi idije naa lo faa, ti wọn fi yan orilẹede Naijiria fun ifẹsẹwọnsẹ naa.


Orilẹ-ede Poland yoo koju orilẹ-ede Senegal, Colombia ati Japan ni ipele akọkọ idije ife ẹyẹ agbaye.
Ifẹsẹwọnsẹ rẹ pẹlu orilẹ-ede Naijiria yoo fun lanfani lati seto ọna ti yoo gba koju ikọ agbabọọlu orilẹ-ede Senegal.


Lewandosky ni igbagbọ awọn alasẹ ere bọọlu lorilẹ-ede Poland ni wi pe ilana gbigba bọọlu orilẹ-ede Naijiria ati orilẹ-ede Senegal ti wọn yoo koju ko fi bẹẹ yatọ si ara wọn.
Bakan naa ni Poland yoo tun waako pẹlu ikọ agbabọọlu orilẹ-ede South korea lati fi gbaradi fun ifẹsẹwọnsẹ ti yoo waye laarin oun ati orilẹ-ede Japan nibi idije ife ẹyẹ agbaye kan naa.

Ibudo iroyin: BBCYoruba

No comments:

Post a Comment