Olukọni ikọ agbabọọlu Super Eagles, Gernot Rhor ti sọ wi pe bi bibori Poland ninu ifẹsẹwọsẹ igbaradi fun idijẹ ife ẹyẹ agbaye ko tumọ si pe Naijiria le gba ife ẹyẹ naa.
Vitor Moses lo ba Naijiria jẹ bọọlu nigba ti orilẹede ọhun na Poland pẹlu ami ayo kan s'odo ninu ifewọnsẹ ti wọn gba l'ọjọ Ẹti.
Alakoso ikọ agbabọọlu orilẹ-ede naa s'apejuwe awọn agbabọọlu Naijiria ọhun gẹgẹ bi ọdọ ti wọn ni awọn oludari laarin wọn.
Ọgbẹni Rohr sọ wipe ti wọn ba tẹsiwaju pẹlu iwa irẹlẹ ati iṣẹ
takun-takun lati tun ere bọọlu wọn ṣe, wọn yoo ni ireti to pọ gan
Sugbọn olukọni naa sọ wipe ewe olubori ti Naijiria ja nibi ifẹsẹwọnsẹ rẹ
pelu Argentina ati Poland ( ti wọn wa ninu orilẹede mẹwa to mọ bọọlu
gba ju lagbaye) ko tumọ si pe Naijiria ti di ọkan lara awọn orilẹede to
le gba ife ẹyẹ agbaye nun.
No comments:
Post a Comment