Ninu ilakaka ki awọn eeyan ilu Eko le wa ni ilera-ara, atipe ki iku aboyun
le dinku ni ijọba ipinlẹ Eko ṣe kọ ile-iwosan to n risi irufẹ nnkan bayi.
Ile-iwosan yi ni wọn ni o wa fun awọn aboyun ọdọ nikan eyi ti wọn ma lẹtọ lati
gba imọran nipa itọju ara ninu oyun, imọran nipa oyun ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Nigbati wọn n ṣi ile-iwosan naa, oludamọran fun gomina lori ilera-ara,
Dokita Fẹmi Ọnanuga jẹ ko di mimọ pe ọpọ eeyan ni ko mọ itọju aboyun ati pe awọn
ọdọ iwoyi o mọ nnkan kan nipa ọmọ-bibi. O ni awọn ọdọmọ binrin pupọ lo n ni
oyun nisin to si jẹ pe wọn ko fẹ. O ni ile-iwosan yi ma ni anfani lati ṣe awọn
iṣẹ kan kan bii oyun yiyọ nitori ọpọ eeyan lo n bimọ ti wọn ko fẹ ati pe eyi ma
n nipa lori eto ilu.
O ni awọn ṣi ma kọ irufẹ ile-iwosan bayi si gbogbo igberiko ilu Eko. Awọn
eeyan ti n fi ọdun ọkan wọn han nitori oyun ṣiṣẹ ti wọn sọ pe ile-iwosan naa ma
le ṣe.

No comments:
Post a Comment