Friday, September 15, 2017

OBINRIN DI AARẸ LORILẸ-EDE SINGAPORE






Arabinrin Halimah  Yacob ni iroyin gbe pe o ti di aarẹ kẹjọ to ma jẹ ni orilẹ-ede Singapore ninu idibo ti ko ni ẹni to ba duu. Ẹni ọmọ ọdun 63 naa ni igbimọ to n ri si idibo ni orilẹ-ede naa ri pe o kun oju oṣuwọn laarin awọn mẹta ti wọn fi orukọ silẹ, awọn meji toku; Salleh Marican ati Farid Khan.

Arabinrin Yacob ni o ti jẹ agbẹnusọ ile-igbimọ orilẹ-ede naa ri. Awọn meji ti wọn ja kulẹ ni wọn sọ pe wọn ni owo to to 500 million singapore dollar ninu ile-iṣẹ aladani eyi to lodi si ofin orilẹ-ede Singapore.

Ọpọ eniyn lo ti bu ẹnu atẹ lu bi arabimrim naa ṣe di aarẹ amọ arabinrin Yacob sọ pe ijọba gbogbo eniyan ni ijọba toun. Bo tilẹ jẹ pe a kan ma ṣaboju toawọn ohun ini orilẹ-ede Singapore ni, ko ni agbara lati da aṣẹ pa. Wọn ma ṣe ibura fun ni ọla, ẹni to jẹ aarẹ gbẹyin ni Ọgbẹni Yusof Ishak.